OLUWA jọba; jẹ ki awọn enia ki o wariri: o joko lori awọn kerubu; ki aiye ki o ta gbọ̀ngbọ́n. Oluwa tobi ni Sioni: o si ga jù gbogbo orilẹ-ède lọ. Ki nwọn ki o yìn orukọ rẹ ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru; mimọ́ li on. Agbara ọba fẹ idajọ pẹlu, iwọ fi idi aiṣegbe mulẹ; iwọ nṣe idajọ ati ododo ni Jakobu. Ẹ gbé Oluwa Ọlọrun wa ga, ki ẹ si foribalẹ nibi apoti itisẹ rẹ̀: mimọ́ li on. Mose ati Aaroni ninu awọn alufa rẹ̀, ati Samueli ninu awọn ti npè orukọ rẹ̀: nwọn ke pè Oluwa, o si da wọn lohùn. O ba wọn sọ̀rọ ninu ọwọ̀n awọsanma: nwọn pa ẹri rẹ̀ mọ́ ati ilana ti o fi fun wọn. Iwọ da wọn lohùn, Oluwa Ọlọrun wa: iwọ li Ọlọrun ti o dariji wọn, ti o si san ẹsan iṣẹ wọn. Ẹ gbé Oluwa Ọlọrun wa ga, ki ẹ si ma sìn nibi òke mimọ́ rẹ̀; nitori Oluwa Ọlọrun wa mimọ́ ni.
Kà O. Daf 99
Feti si O. Daf 99
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 99:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò