O. Daf 97

97
Ọlọrun Ọba Atóbijù
1OLUWA jọba; ki aiye ki o yọ̀; jẹ ki inu ọ̀pọlọpọ erekuṣu ki o dùn.
2Awọsanma ati okunkun yi i ka: ododo ati idajọ ni ibujoko itẹ́ rẹ̀.
3Iná ṣaju rẹ̀, o si jo awọn ọta rẹ̀ yika kiri.
4Manamana rẹ̀ kọ imọlẹ si aiye: aiye ri i, o si wariri.
5Awọn òke nyọ́ bi ida niwaju Oluwa, niwaju Oluwa gbogbo aiye:
6Ọrun fi ododo rẹ̀ hàn, gbogbo orilẹ-ède si ri ogo rẹ̀.
7Oju yio tì gbogbo awọn ti nsìn ere fifin, ẹniti nfi ere ṣe ileri ara wọn: ẹ ma sìn i, gbogbo ẹnyin ọlọrun.
8Sioni gbọ́, inu rẹ̀ si dùn; awọn ọmọbinrin Juda si yọ̀, Oluwa, nitori idajọ rẹ.
9Nitoripe Iwọ Oluwa, li o ga jù gbogbo aiye lọ: Iwọ li a gbé ga jù gbogbo oriṣa lọ.
10Ẹnyin ti o fẹ Oluwa, ẹ korira ibi: o pa ọkàn awọn enia mimọ́ rẹ̀ mọ́: o gbà wọn li ọwọ awọn enia buburu.
11A funrugbin imọlẹ fun olododo, ati inu didùn fun alaiya diduro.
12Ẹ yọ̀ niti Oluwa, ẹnyin olododo; ki ẹ si ma dupẹ ni iranti ìwa-mimọ́ rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 97: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀