ẸWÁ, ẹ jẹ ki a kọrin si Oluwa: ẹ jẹ ki a hó iho ayọ̀ si apata igbala wa. Ẹ jẹ ki a fi ọpẹ wá si iwaju rẹ̀, ki a si fi orin mimọ́ hó iho ayọ̀ si ọdọ rẹ̀. Nitori Oluwa, Ọlọrun ti o tobi ni, ati Ọba ti o tobi jù gbogbo oriṣa lọ, Ni ikawọ ẹniti ibi ọgbun ilẹ wà: giga awọn òke nla ni tirẹ̀ pẹlu. Tirẹ̀ li okun, on li o si dá a: ọwọ rẹ̀ li o si dá iyangbẹ ilẹ. Ẹ wá, ẹ jẹ ki a wolẹ, ki a tẹriba: ẹ jẹ ki a kunlẹ niwaju Oluwa, Ẹlẹda wa.
Kà O. Daf 95
Feti si O. Daf 95
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 95:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò