O. Daf 83

83
Adura Ìṣẹ́gun
1MAṢE dakẹ, Ọlọrun: máṣe pa ẹnu rẹ mọ́, ki o má si ṣe duro jẹ, Ọlọrun.
2Sa wò o, awọn ọta rẹ nrọkẹ̀kẹ: awọn ti o korira rẹ ti gbé ori soke.
3Nwọn ti gbimọ̀ arekereke si awọn enia rẹ, nwọn si ti gbèro si awọn ẹni-ìkọ̀kọ̀ rẹ.
4Nwọn ti wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a ke wọn kuro lati má wà li orilẹ-ède; ki orukọ Israeli ki o máṣe si ni iranti mọ́.
5Nitoriti nwọn ti gbimọ̀ pọ̀ ṣọkan: nwọn ti dimọlu si ọ.
6Agọ Edomu, ati ti awọn ọmọ Iṣmaeli; ti Moabu, ati awọn ọmọ Hagari.
7Gebali, ati Ammoni, ati Amaleki: awọn ara Filistia pẹlu awọn ara Tire;
8Assuri pẹlu dapọ̀ mọ wọn: nwọn ràn awọn ọmọ Loti lọwọ.
9Ṣe wọn bi o ti ṣe awọn ara Midiani; bi Sisera, bi Jabini, li odò Kiṣoni.
10Ẹniti o ṣegbe ni Endori: nwọn di àtan fun ilẹ.
11Ṣe awọn ọlọla wọn bi Orebu ati bi Sebu: ani, gbogbo awọn ọmọ-alade wọn bi Seba ati Salmuna.
12Awọn ti o wipe, Ẹ jẹ ki a gbà ibugbe Ọlọrun wọnni fun ara wa ni ini.
13Ọlọrun mi, ṣe wọn bi ãjà; bi akeku koriko niwaju afẹfẹ.
14Bi iná ti ijo igbo, ati bi ọwọ́ iná ti imu òke-nla gbiná;
15Bẹ̃ni ki o fi ẹ̀fufu rẹ ṣe inunibini si wọn, ki o si fi ìji rẹ dẹrubà wọn.
16Fi ìtiju kún wọn li oju: ki nwọn o le ma ṣe afẹri orukọ rẹ, Oluwa.
17Ki nwọn ki o dãmu ki a si pọ́n wọn loju lailai; nitõtọ, ki a dojutì wọn, ki nwọn ki o ṣegbé.
18Ki awọn enia ki o le mọ̀ pe iwọ, orukọ ẹni-kanṣoṣo ti ijẹ Jehofah, iwọ li Ọga-ogo lori aiye gbogbo.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 83: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀