O. Daf 75

75
Ọlọrun Onídàájọ́
1ỌLỌRUN, iwọ li awa fi ọpẹ fun, iwọ li awa fi ọpẹ fun nitori orukọ rẹ sunmọ itosi, iṣẹ iyanu rẹ fi hàn.
2Nigbati akokò mi ba de, emi o fi otitọ ṣe idajọ.
3Aiye ati gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀ warìri: emi li o rù ọwọ̀n rẹ̀.
4Emi wi fun awọn agberaga pe, Ẹ máṣe gbéraga mọ́: ati fun awọn enia buburu pe, Ẹ máṣe gbé iwo nì soke.
5Ẹ máṣe gbé iwo nyin ga: ẹ máṣe fi ọrùn lile sọ̀rọ.
6Nitori ti igbega kò ti ìla-õrùn wá, tabi ni ìwọ-õrùn, bẹ̃ni kì iṣe lati gusu wá.
7Ṣugbọn Ọlọrun li onidajọ: o sọ ọkan kalẹ, o gbé ẹlomiran leke.
8Nitoripe li ọwọ Oluwa li ago kan wà, ọti-waini na si pọ́n: o kún fun àdalu: o si dà jade ninu rẹ̀; ṣugbọn gèdẹgẹdẹ rẹ̀, gbogbo awọn enia buburu aiye ni yio fun u li afun-mu.
9Ṣugbọn emi o ma sọ titi lai, emi o ma kọrin iyìn si Ọlọrun Jakobu.
10Gbogbo iwo awọn enia buburu li emi o ke kuro; ṣugbọn iwo awọn olododo li emi o gbé soke.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 75: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀