O. Daf 57

57
Adura Ìrànlọ́wọ́
Orin Dafidi, nigbati o sa kuro lọwọ Saulu sinu iho-okuta.
1ṢÃNU fun mi: Ọlọrun, ṣãnu fun mi: nitoriti ọkàn mi gbẹkẹle ọ: lõtọ, li ojiji iyẹ-apa rẹ li emi o fi ṣe àbo mi, titi wahala wọnyi yio fi rekọja.
2Emi o kigbe pe Ọlọrun Ọga-ogo; si Ọlọrun ti o ṣe ohun gbogbo fun mi.
3On o ranṣẹ lati ọrun wá, yio si gbà mi bi ẹniti nfẹ gbe mi mì tilẹ nkẹgàn mi. Ọlọrun yio rán ãnu rẹ̀ ati otitọ rẹ̀ jade.
4Ọkàn mi wà lãrin awọn kiniun: emi tilẹ dubulẹ lãrin awọn ti o gbiná, eyinì ni awọn ọmọ enia, ehín ẹniti iṣe ọ̀kọ ati ọfa, ati ahọn wọn, idà mimú.
5Gbigbega ni ọ, Ọlọrun, jù ọrun lọ; ati ogo rẹ jù gbogbo aiye lọ.
6Nwọn ti ta àwọn silẹ fun ẹsẹ mi: nwọn tẹ ori ọkàn mi ba: nwọn ti wà iho silẹ niwaju mi, li ãrin eyina li awọn tikarawọn jìn si.
7Ọkàn mi ti mura, Ọlọrun, ọkàn mi ti mura: emi o kọrin, emi o si ma kọrin iyìn.
8Jí, iwọ ogo mi; jí, ohun-èlo orin ati duru: emi tikarami yio si jí ni kutukutu.
9Emi o ma yìn ọ, Oluwa lãrin awọn enia: emi o si ma kọrin si ọ lãrin awọn orilẹ-ède.
10Nitoriti ãnu rẹ pọ̀ de ọrun, ati otitọ rẹ de awọsanma.
11Gbigbega ni ọ, Ọlọrun, jù awọn ọrun lọ ati ogo rẹ jù gbogbo aiye lọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 57: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀