O. Daf 55:1-14

O. Daf 55:1-14 YBCV

FETI si adura mi, Ọlọrun; má si ṣe fi ara rẹ pamọ kuro ninu ẹ̀bẹ mi. Fiye si mi, ki o si da mi lohùn: ara mi kò lelẹ ninu aroye mi, emi si npariwo; Nitori ohùn ọta nì, nitori inilara enia buburu: nitoriti nwọn mu ibi ba mi, ati ni ibinu, nwọn dẹkun fun mi. Aiya dùn mi gidigidi ninu mi: ipaiya ikú si ṣubu lù mi. Ibẹ̀ru ati ìwárìrì wá si ara mi, ati ibẹ̀ru ikú bò mi mọlẹ. Emi si wipe, A! iba ṣe pe emi ni iyẹ-apa bi àdaba! emi iba fò lọ, emi a si simi. Kiyesi i, emi iba rìn lọ si ọ̀na jijin rére, emi a si ma gbe li aginju. Emi iba yara sa asala mi kuro ninu ẹfufu lile ati iji na. Oluwa, ṣe iparun, ki o si yà wọn li ahọn: nitori ti mo ri ìwa agbara ati ijà ni ilu na. Ọsan ati oru ni nwọn fi nrìn odi rẹ̀ kiri: ìwa-ika pẹlu ati ikãnu mbẹ li arin rẹ̀. Ìwa buburu mbẹ li arin rẹ̀: ẹ̀tan ati eke kò kuro ni igboro rẹ̀. Nitoriti kì iṣe ọta li o gàn mi: njẹ emi iba pa a mọra: bẹ̃ni kì iṣe ẹniti o korira mi li o gbé ara rẹ̀ ga si mi; njẹ emi iba fi ara mi pamọ́ kuro lọdọ rẹ̀: Ṣugbọn iwọ ni, ọkunrin ọ̀gba mi, amọ̀na mi, ati ojulumọ mi. Awa jumọ gbimọ didùn, awa si kẹgbẹ rìn wọ̀ ile Ọlọrun lọ.