O. Daf 5:1-12

O. Daf 5:1-12 YBCV

FI eti si ọ̀rọ mi, Oluwa, kiyesi aroye mi. Fi eti si ohùn ẹkún mi, Ọba mi, ati Ọlọrun mi: nitoripe ọdọ rẹ li emi o ma gbadura si. Ohùn mi ni iwọ o gbọ́ li owurọ, Oluwa, li owurọ li emi o gbà adura mi si ọ, emi o si ma wòke. Nitori ti iwọ kì iṣe Ọlọrun ti iṣe inu-didùn si ìwa buburu: bẹ̃ni ibi kò le ba ọ gbe. Awọn agberaga kì yio le duro niwaju rẹ: iwọ korira gbogbo awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ. Iwọ o pa awọn ti nṣe eke run; Oluwa yio korira awọn ẹni-ẹ̀jẹ ati ẹni-ẹ̀tan. Ṣugbọn bi o ṣe ti emi, emi o wá sinu ile rẹ li ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ: ninu ẹ̀ru rẹ li emi o tẹriba si iha tempili mimọ́ rẹ. Tọ́ mi, Oluwa, ninu ododo rẹ, nitori awọn ọta mi: mu ọ̀na rẹ tọ́ tàra niwaju mi. Nitori ti otitọ kan kò si li ẹnu ẹnikẹni wọn; ikakika ni iha inu wọn; isa-okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi npọ́nni. Iwọ da wọn lẹbi, Ọlọrun; ki nwọn ki o ti ipa ìmọ ara wọn ṣubu; já wọn kuro nitori ọ̀pọlọpọ irekọja wọn; nitori ti nwọn ti ṣọ̀tẹ si ọ. Nigbana ni gbogbo awọn ti ngbẹkẹle ọ yio yọ̀; lai nwọn o ma ho fun ayọ̀, nitoriti iwọ dabobo wọn: ati awọn ti o fẹ orukọ rẹ pẹlu yio ma yọ̀ ninu rẹ. Nitori iwọ, Oluwa, ni yio bukún fun olododo; oju-rere ni iwọ o fi yi i ka bi asà.