Fetí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA; kíyèsí ìmí ẹ̀dùn mi. Fetí sí igbe mi, Ọba mi ati Ọlọrun mi, nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí. OLUWA, o óo gbọ́ ohùn mi ní òwúrọ̀, ní òwúrọ̀ ni n óo máa sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún ọ; èmi óo sì máa ṣọ́nà. Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọrun tí inú rẹ̀ dùn sí ìwà burúkú; àwọn ẹni ibi kò sì lè bá ọ gbé. Àwọn tí ń fọ́nnu kò lè dúró níwájú rẹ; o kórìíra gbogbo àwọn aṣebi. O máa ń pa àwọn òpùrọ́ run; OLUWA, o kórìíra àwọn apani ati ẹlẹ́tàn. Ṣugbọn nípa ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, èmi óo wọ inú ilé rẹ; n óo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ wólẹ̀, n óo sì kọjúsí tẹmpili mímọ́ rẹ. OLUWA, tọ́ mi sọ́nà òdodo rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi; jẹ́ kí ọ̀nà rẹ hàn kedere níwájú mi. Nítorí kò sí òtítọ́ kan lẹ́nu wọn; ìparun ni ó wà ninu ọkàn wọn. Isà òkú tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn; ẹnu wọn kún fún ìpọ́nni ẹ̀tàn. Dá wọn lẹ́bi, Ọlọrun, kí o sì fìyà jẹ wọ́n; jẹ́ kí ìgbìmọ̀pọ̀ wọn ó gbé wọn ṣubú. Ta wọ́n nù nítorí ọ̀pọ̀ ìrékọjá wọn, nítorí pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. Ṣugbọn jẹ́ kí inú gbogbo àwọn tí ó sá di ọ́ ó dùn, kí wọn ó máa kọrin ayọ̀ títí lae. Dáàbò bò wọ́n, kí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ sì máa yọ̀ ninu rẹ. Nítorí ìwọ OLUWA a máa bukun àwọn olódodo; ò sì máa fi ojurere rẹ tí ó dàbí apata dáàbò bò wọ́n.
Kà ORIN DAFIDI 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 5:1-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò