O. Daf 47

47
Ọba Àwọn Ọba
1ẸNYIN enia, gbogbo ẹ ṣapẹ; ẹ fi ohùn ayọ̀ hó ihó iṣẹgun si Ọlọrun.
2Nitori Oluwa Ọga-ogo li ẹ̀ru; on li ọba nla lori ilẹ-aiye gbogbo.
3On ni yio ṣẹ́ awọn enia labẹ wa, ati awọn orilẹ-ède li atẹlẹsẹ wa.
4On ni yio yàn ilẹ-ini wa fun wa, ọlá Jakobu, ẹniti o fẹ.
5Ọlọrun gòke lọ ti on ti ariwo, Oluwa, ti on ti iró ipè.
6Ẹ kọrin iyìn si Ọlọrun, ẹ kọrin iyìn: ẹ kọrin iyìn si Ọba wa, ẹ kọrin iyìn.
7Nitori Ọlọrun li Ọba gbogbo aiye: ẹ fi oye kọrin iyìn.
8Ọlọrun jọba awọn keferi: Ọlọrun joko lori itẹ ìwa-mimọ́ rẹ̀.
9Awọn alade awọn enia kó ara wọn jọ, ani awọn enia Ọlọrun Abrahamu: nitori asà aiye ti Ọlọrun ni: on li a gbe leke jọjọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 47: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀