O. Daf 45

45
Orin Igbeyawo Ọmọ Ọba
1AIYA mi nhumọ̀ ọ̀ran rere: emi nsọ ohun ti mo ti ṣe, fun ọba ni: kalamu ayawọ akọwe li ahọn mi.
2Iwọ yanju jù awọn ọmọ enia lọ: a dà ore-ọfẹ si ọ li ète: nitorina li Ọlọrun nbukún fun ọ lailai.
3San idà rẹ mọ idi rẹ, Alagbara julọ, ani ogo rẹ ati ọlá-nla rẹ.
4Ati ninu ọlánlá rẹ ma gẹṣin lọ li alafia, nitori otitọ ati ìwa-tutu ati ododo; ọwọ ọtún rẹ yio si kọ́ ọ li ohun ẹ̀ru.
5Ọfa rẹ mu li aiya awọn ọta ọba; awọn enia nṣubu nisalẹ ẹsẹ rẹ.
6Ọlọrun, lai ati lailai ni itẹ́ rẹ: ọpá-alade ijọba rẹ, ọpá-alade otitọ ni.
7Iwọ fẹ ododo, iwọ korira ìwa-buburu: nitori na li Ọlọrun, Ọlọrun rẹ, ṣe fi àmi ororo ayọ̀ yà ọ ṣolori awọn ọ̀gba rẹ.
8Gbogbo aṣọ rẹ li o nrun turari, ati aloe, ati kassia, lati inu ãfin ehin-erin jade ni nwọn gbe nmu ọ yọ̀.
9Awọn ọmọbinrin awọn alade wà ninu awọn ayanfẹ rẹ: li ọwọ ọtún rẹ li ayaba na gbe duro ninu wura Ofiri.
10Dẹti silẹ, ọmọbinrin, si ronu, si dẹ eti rẹ silẹ! gbagbe awọn enia rẹ, ati ile baba rẹ!
11Bẹ̃li Ọba yio fẹ ẹwà rẹ gidigidi: nitori on li Oluwa rẹ; ki iwọ ki o si ma sìn i.
12Ọmọbinrin Tire ti on ti ọrẹ; ati awọn ọlọrọ̀ ninu awọn enia yio ma bẹ̀bẹ oju-rere rẹ.
13Ti ogo ti ogo li ọmọbinrin ọba na ninu ile: iṣẹ wura ọnà abẹrẹ li aṣọ rẹ̀.
14Ninu aṣọ iṣẹ ọnà abẹrẹ li a o mu u tọ̀ ọba wá: awọn wundia, ẹgbẹ rẹ̀ ti ntọ̀ ọ lẹhin li a o mu tọ̀ ọ wá.
15Pẹlu inu didùn ati pẹlu ayọ̀ li a o fi mu wọn wá: nwọn o si wọ̀ ãfin ọba lọ.
16Nipò awọn baba rẹ li awọn ọmọ rẹ yio wà, ẹniti iwọ o ma fi jẹ oye lori ilẹ gbogbo.
17Emi o ma ṣe orukọ rẹ ni iranti ni iran gbogbo: nitorina li awọn enia yio ṣe ma yìn ọ lai ati lailai.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 45: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa