O. Daf 43

43
Adura Ẹni tí A Lé ní Ìlú
1ṢE idajọ mi, Ọlọrun, ki o si gbà ọ̀ran mi rò si alailãnu orilẹ-ède: gbà mi lọwọ ẹlẹtan ati ọkunrin alaiṣõtọ nì.
2Nitori iwọ li Ọlọrun agbara mi: ẽṣe ti iwọ fi ṣa mi tì? ẽṣe ti emi fi nrìn ni igbawẹ nitori inilara ọta nì.
3Rán imọlẹ rẹ ati otitọ rẹ jade, ki nwọn ki o ma ṣe amọna mi: ki nwọn ki o mu mi gùn òke mimọ́ rẹ, ati sinu agọ rẹ wọnni.
4Nigbana li emi o lọ si ibi pẹpẹ Ọlọrun, sọdọ Ọlọrun ayọ̀ nla mi: nitõtọ, lara duru li emi o ma yìn ọ, Ọlọrun, Ọlọrun mi.
5Ẽṣe ti ori rẹ fi tẹ̀ba, iwọ ọkàn mi? ẽṣe ti ara rẹ kò fi lelẹ ninu mi? iwọ ṣe ireti niti Ọlọrun: nitoriti emi o sa ma yìn i sibẹ, ẹniti iṣe iranlọwọ oju mi, ati Ọlọrun mi.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 43: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀