A ṣe ìlana ẹsẹ enia lati ọwọ Oluwa wá: o si ṣe inu didùn si ọ̀na rẹ̀. Bi o tilẹ ṣubu, a kì yio ta a nù kuro patapata; nitoriti Oluwa di ọwọ rẹ̀ mu. Emi ti wà li ewe, emi si dagba; emi kò ti iri ki a kọ̀ olododo silẹ, tabi ki iru-ọmọ rẹ̀ ki o ma ṣagbe onjẹ. Alãnu li on nigbagbogbo, a ma wín ni: a si ma busi i fun iru-ọmọ rẹ̀. Kuro ninu ibi ki o si ma ṣe rere; ki o si ma joko lailai. Nitoriti Oluwa fẹ idajọ, kò si kọ̀ awọn enia mimọ́ rẹ̀ silẹ; a si pa wọn mọ́ lailai: ṣugbọn iru-ọmọ awọn enia buburu li a o ke kuro. Olododo ni yio jogun aiye, yio si ma gbe inu rẹ̀ lailai. Ẹnu olododo ni ima sọ̀rọ ọgbọ́n, ahọn rẹ̀ a si ma sọ̀rọ idajọ. Ofin Ọlọrun rẹ̀ mbẹ li aiya rẹ̀; ọkan ninu ìrin rẹ̀ kì yio yẹ̀. Ẹni buburu nṣọ olododo, o si nwá ọ̀na lati pa a. Oluwa kì yio fi i le e lọwọ, kì yio si da a lẹbi, nigbati a ba nṣe idajọ rẹ̀. Duro de Oluwa, ki o si ma pa ọ̀na rẹ̀ mọ́, yio si gbé ọ leke lati jogun aiye: nigbati a ba ké awọn enia buburu kuro, iwọ o ri i. Emi ti nri enia buburu, ẹni ìwa-ika, o si fi ara rẹ̀ gbilẹ bi igi tutu nla. Ṣugbọn o kọja lọ, si kiyesi i, kò sí mọ: lõtọ emi wá a kiri, ṣugbọn a kò le ri i. Ma kiyesi ẹni pipé, ki o si ma wò ẹni diduro ṣinṣin: nitori alafia li opin ọkunrin na. Ṣugbọn awọn alarekọja li a o parun pọ̀; iran awọn enia buburu li a o ké kuro. Ṣugbọn lati ọwọ Oluwa wá ni igbala awọn olododo; on li àbo wọn ni igba ipọnju. Oluwa yio si ràn wọn lọwọ, yio si gbà wọn, yio si gbà wọn lọwọ enia buburu, yio si gbà wọn la, nitoriti nwọn gbẹkẹle e.
Kà O. Daf 37
Feti si O. Daf 37
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 37:23-40
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò