IREKỌJA enia buburu wi ninu ọkàn mi pe; ẹ̀ru Ọlọrun kò si niwaju rẹ̀. Nitoriti o npọ́n ara rẹ̀ li oju ara rẹ̀, titi a o fi ri ẹ̀ṣẹ rẹ̀ lati korira; Ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ li ẹ̀ṣẹ on ẹ̀tan: o ti fi ọgbọ́n ati iṣe rere silẹ, O ngbèro ìwa-ika lori ẹni rẹ̀: o gba ọ̀na ti kò dara; on kò korira ibi. Oluwa, ãnu rẹ de ọrun; otitọ rẹ de awọsanma. Ododo rẹ dabi awọn òke Ọlọrun; idajọ rẹ dabi ibu nla: Oluwa, iwọ pa enia ati ẹranko mọ́. Ọlọrun, iṣeun-ifẹ rẹ ti dara to! nitori na li awọn ọmọ enia yio ma gbẹkẹ wọn le abẹ ojiji iyẹ-apa rẹ. Ororo ile rẹ yio tẹ wọn lọrùn gidigidi; iwọ o si mu wọn mumi ninu odò ifẹ rẹ. Nitori pe pẹlu rẹ li orisun ìye wà: ninu imọlẹ rẹ li awa o ma ri imọlẹ. Mu iṣeun ifẹ rẹ pẹ si awọn ti o mọ̀ ọ; ati ododo rẹ fun awọn alaiyà diduro. Máṣe jẹ ki ẹsẹ agberaga ki o wá si mi, ki o má si jẹ ki ọwọ enia buburu ki o ṣi mi ni ipò. Nibẹ li awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ gbe ṣubu: a rẹ̀ wọn silẹ, nwọn kì yio si le dide.
Kà O. Daf 36
Feti si O. Daf 36
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 36:1-12
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò