O. Daf 23
23
OLUWA ni Olùṣọ́-agutan mi
1OLUWA li Oluṣọ-agutan mi; emi kì yio ṣe alaini.
2O mu mi dubulẹ ninu papa-oko tutù; o mu mi lọ si iha omi didakẹ rọ́rọ́.
3O tù ọkàn mi lara; o mu mi lọ nipa ọ̀na ododo nitori orukọ rẹ̀.
4Nitõtọ, bi mo tilẹ nrìn larin afonifoji ojiji ikú, emi kì yio bẹ̀ru ibi kan; nitori ti Iwọ pẹlu mi; ọgọ rẹ ati ọpá rẹ nwọn ntù mi ninu.
5Iwọ tẹ́ tabili onjẹ silẹ niwaju mi li oju awọn ọta mi; iwọ dà ororo si mi li ori; ago mi si kún akúnwọsilẹ.
6Nitotọ, ire ati ãnu ni yio ma tọ̀ mi lẹhin li ọjọ aiye mi gbogbo; emi o si ma gbe inu ile Oluwa lailai.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 23: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.