AWỌN ọrun nsọ̀rọ ogo Ọlọrun; ati ofurufu nfi iṣẹ ọwọ rẹ̀ han. Ọjọ de ọjọ nfọhùn, ati oru de oru nfi ìmọ hàn. Kò si ohùn kan tabi ède kan, nibiti a kò gbọ́ iró wọn. Iró wọn la gbogbo aiye ja, ati ọ̀rọ wọn de opin aiye: ninu wọn li o gbe pagọ fun õrun. Ti o dabi ọkọ iyawo ti njade ti iyẹwu rẹ̀ wá, ti o si yọ̀ bi ọkunrin alagbara lati sure ije. Ijadelọ rẹ̀ ni lati opin ọrun wá, ati ayika rẹ̀ si de ipinlẹ rẹ̀: kò si si ohun ti o fi ara pamọ́ kuro ninu õru rẹ̀.
Kà O. Daf 19
Feti si O. Daf 19
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 19:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò