O. Daf 18:16-36

O. Daf 18:16-36 YBCV

O ranṣẹ́ lati òke wá, o mu mi, o fà mi jade wá lati inu omi nla. O gbà mi lọwọ ọta mi alagbara, ati lọwọ awọn ti o korira mi; nitori nwọn li agbara jù mi lọ. Nwọn dojukọ mi li ọjọ ipọnju mi: ṣugbọn Oluwa li alafẹhintì mi. O mu mi jade pẹlu sinu ibi nla; o gbà mi nitori inu rẹ̀ dùn si mi. Oluwa san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi; gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ mi li o san a fun mi. Nitori mo ti nkiye si ọ̀na Oluwa, emi kò fi ìka yà kuro lọdọ Ọlọrun mi. Nitori pe gbogbo idajọ rẹ̀ li o wà niwaju mi, bẹ̃li emi kò si yẹ̀ ofin rẹ̀ kuro lọdọ mi. Emi si duro ṣinṣin pẹlu rẹ̀, emi si paramọ kuro lara ẹ̀ṣẹ mi. Nitorina li Oluwa ṣe san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi, gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ mi li oju rẹ̀. Fun alãnu ni iwọ o fi ara rẹ hàn li alãnu; fun ẹniti o duro-ṣinṣin ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni diduro-ṣinṣin. Fun ọlọkàn-mimọ́ ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni ọlọkàn-mimọ́; ati fun ọlọkàn-wiwọ ni iwọ o fi ara rẹ hàn li onroro. Nitori iwọ o gbà awọn olupọnju; ṣugbọn iwọ o sọ oju igberaga kalẹ. Nitori iwọ ni yio tàn fitila mi: Oluwa Ọlọrun mi yio tàn imọlẹ si òkunkun mi. Nitori pe pẹlu rẹ emi sure là inu ogun lọ: ati pẹlu Ọlọrun mi emi fò odi kan. Bi o ṣe ti Ọlọrun ni, ọ̀na rẹ̀ pé: a ti ridi ọ̀rọ Oluwa: on li apata fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e. Nitori pe tani iṣe Ọlọrun, bikoṣe Oluwa? tabi tani iṣe apáta bikoṣe Ọlọrun wa? Ọlọrun li o fi agbara dì mi li amure, o si mu ọ̀na mi pé. O ṣe ẹsẹ mi bi ẹsẹ àgbọnrín, o si gbé mi kà ibi giga mi. O kọ́ ọwọ mi li ogun jija, tobẹ̃ ti apa mi fà ọrun idẹ. Iwọ ti fi asà igbala rẹ fun mi pẹlu: ọwọ ọ̀tun rẹ si gbé mi duro, ati ìwa-pẹlẹ rẹ sọ mi di nla. Iwọ sọ ìrin ẹsẹ mi di nla nisalẹ mi, ki kóko-ẹsẹ mi ki o máṣe yẹ̀.