Ẹ fi iyìn fun Oluwa, Ẹ fi iyìn fun Oluwa lati ọrun wá; ẹ fi iyìn fun u ni ibi giga. Ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin angeli rẹ̀; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin ọmọ-ogun rẹ̀. Ẹ fi iyìn fun u, õrun ati oṣupa; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin irawọ imọlẹ. Ẹ fi iyìn fun u, ẹnyin ọrun awọn ọrun, ati ẹnyin omi ti mbẹ loke ọrun. Jẹ ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa; nitori ti on paṣẹ, a si da wọn. O si fi idi wọn mulẹ lai ati lailai; o si ti ṣe ilana kan ti kì yio kọja. Ẹ yìn Oluwa lati aiye wá, ẹnyin erinmi, ati gbogbo ibu-omi; Iná ati yinyin òjo-didì ati ikũku; ìji mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ; Ẹnyin òke nla, ati gbogbo òke kekere; igi eleso, ati gbogbo igi Kedari; Ẹranko, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin; ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ́ ti nfò; Awọn ọba aiye, ati gbogbo enia; ọmọ-alade, ati gbogbo onidajọ aiye; Awọn ọdọmọkunrin ati awọn wundia, awọn arugbo enia ati awọn ọmọde; Ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa; nitori orukọ rẹ̀ nikan li o li ọlá; ogo rẹ̀ bori aiye on ọrun. O si gbé iwo kan soke fun awọn enia rẹ̀, iyìn fun gbogbo enia mimọ́ rẹ̀; ani awọn ọmọ Israeli, awọn enia ti o sunmọ ọdọ rẹ̀. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.
Kà O. Daf 148
Feti si O. Daf 148
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 148:1-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò