Ibukún ni fun ẹniti o ni Ọlọrun Jakobu fun iranlọwọ rẹ̀, ireti ẹniti mbẹ lọdọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀: Ẹniti o da ọrun on aiye, okun ati ohun ti o wà ninu wọn: ẹniti o pa otitọ mọ́ titi aiye: Ẹniti o nṣe idajọ fun ẹni-inilara: ẹniti o nfi onjẹ fun ẹniti ebi npa. Oluwa tú awọn aratubu silẹ: Oluwa ṣi oju awọn afọju: Oluwa gbé awọn ti a tẹ̀ lori ba dide; Oluwa fẹ awọn olododo: Oluwa pa awọn alejo mọ́; o tù awọn alainibaba ati opo lara: ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu ni yio darú. Oluwa yio jọba lailai, ani Ọlọrun rẹ, iwọ Sioni, lati iran-diran gbogbo. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.
Kà O. Daf 146
Feti si O. Daf 146
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 146:5-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò