O. Daf 142

142
Adura Ìrànlọ́wọ́
Orin Dafidi; Adura ti o gbà nigbati o wà ninu iho-okuta.
1OLUWA ni mo fi ohùn mi kigbe pè; ohùn mi ni mo fi mbẹ̀bẹ mi si Oluwa.
2Emi tú aroye mi silẹ niwaju rẹ̀; emi fi iṣẹ́ mi hàn niwaju rẹ̀.
3Nigbati ọkàn mi rẹ̀wẹsi ninu mi, nigbana ni iwọ mọ̀ ipa-ọ̀na mi. Li ọ̀na ti emi nrìn ni nwọn dẹkùn silẹ fun mi nikọ̀kọ.
4Emi wò ọwọ ọtún, mo si ri pe, kò si ẹnikan ti o mọ̀ mi: àbo dẹti fun mi; kò si ẹniti o nãni ọkàn mi.
5Oluwa, iwọ ni mo kigbe pè: emi wipe, iwọ li àbo mi ati ipin mi ni ilẹ alãye.
6Fiyesi igbe mi: nitori ti a rẹ̀ mi silẹ gidigidi: gbà mi lọwọ awọn oninu-nibini mi. Nitori nwọn lagbara ju mi lọ.
7Mu ọkàn mi jade kuro ninu tubu, ki emi ki o le ma yìn orukọ rẹ; awọn olododo yio yi mi ka kiri; nitori iwọ o fi ọ̀pọlọpọ ba mi ṣe.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 142: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀