OLUWA ni mo fi ohùn mi kigbe pè; ohùn mi ni mo fi mbẹ̀bẹ mi si Oluwa. Emi tú aroye mi silẹ niwaju rẹ̀; emi fi iṣẹ́ mi hàn niwaju rẹ̀. Nigbati ọkàn mi rẹ̀wẹsi ninu mi, nigbana ni iwọ mọ̀ ipa-ọ̀na mi. Li ọ̀na ti emi nrìn ni nwọn dẹkùn silẹ fun mi nikọ̀kọ. Emi wò ọwọ ọtún, mo si ri pe, kò si ẹnikan ti o mọ̀ mi: àbo dẹti fun mi; kò si ẹniti o nãni ọkàn mi. Oluwa, iwọ ni mo kigbe pè: emi wipe, iwọ li àbo mi ati ipin mi ni ilẹ alãye. Fiyesi igbe mi: nitori ti a rẹ̀ mi silẹ gidigidi: gbà mi lọwọ awọn oninu-nibini mi. Nitori nwọn lagbara ju mi lọ. Mu ọkàn mi jade kuro ninu tubu, ki emi ki o le ma yìn orukọ rẹ; awọn olododo yio yi mi ka kiri; nitori iwọ o fi ọ̀pọlọpọ ba mi ṣe.
Kà O. Daf 142
Feti si O. Daf 142
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 142:1-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò