O. Daf 136:1-9

O. Daf 136:1-9 YBCV

Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun awọn ọlọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn oluwa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Fun on nikan ti nṣe iṣẹ iyanu nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Fun ẹniti o fi ọgbọ́n da ọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Fun ẹniti o tẹ́ ilẹ lori omi: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Fun ẹniti o dá awọn imọlẹ nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai. Õrùn lati jọba ọsan: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai: Oṣupa ati irawọ lati jọba oru: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú O. Daf 136:1-9