O. Daf 128

128
Ìbẹ̀rù OLUWA lérè
1IBUKÚN ni fun gbogbo ẹniti o bẹ̀ru Oluwa; ti o si nrìn li ọ̀na rẹ̀.
2Nitori ti iwọ o jẹ iṣẹ́ ọwọ rẹ: ibukún ni fun ọ: yio si dara fun ọ.
3Obinrin rẹ yio dabi àjara rere eleso pupọ li arin ile rẹ: awọn ọmọ rẹ yio dabi igi olifi yi tabili rẹ ka.
4Kiyesi i, pe bẹ̃li a o busi i fun ọkunrin na, ti o bẹ̀ru Oluwa.
5Ki Oluwa ki o busi i fun ọ lati Sioni wá, ki iwọ ki o si ma ri ire Jerusalemu li ọjọ aiye rẹ gbogbo.
6Bẹ̃ni ki iwọ ki o si ma ri ati ọmọ-de-ọmọ rẹ: ati alafia lara Israeli.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 128: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀