O. Daf 127

127
Abániṣé ni OLUWA
1BIKOṢEPE Oluwa ba kọ́ ile na, awọn ti nkọ́ ọ nṣiṣẹ lasan: bikoṣepe Oluwa ba pa ilu mọ́, oluṣọ ji lasan.
2Asan ni fun ẹnyin ti ẹ dide ni kutukutu lati pẹ iṣiwọ, lati jẹ onjẹ lãlã: bẹ̃li o nfi ire fun olufẹ rẹ̀ loju orun.
3Kiyesi i, awọn ọmọ ni ini Oluwa: ọmọ inu si li ère rẹ̀.
4Bi ọfà ti ri li ọwọ alagbara, bẹ̃li awọn ọmọ igbà èwe rẹ.
5Ibukún ni fun ọkunrin na ti apo rẹ̀ kún fun wọn: oju kì yio tì wọn, ṣugbọn nwọn o ṣẹgun awọn ọta li ẹnu ọ̀na.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 127: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀