O. Daf 125

125
Ìfọ̀kànbalẹ̀ Àwọn Eniyan OLUWA
1AWỌN ti o gbẹkẹle Oluwa yio dabi òke Sioni, ti a kò le ṣi ni idi, bikoṣepe o duro lailai.
2Bi òke nla ti yi Jerusalemu ka, bẹ̃li Oluwa yi awọn enia rẹ̀ ka lati isisiyi lọ ati titi lailai.
3Nitori ti ọpá awọn enia buburu kì yio bà le ipin awọn olododo: ki awọn olododo ki o má ba fi ọwọ wọn le ẹ̀ṣẹ.
4Oluwa ṣe rere fun awọn ẹni-rere, ati fun awọn ti aiya wọn duro ṣinṣin.
5Bi o ṣe ti iru awọn ti nwọn yà si ipa ọ̀na wiwọ wọn: Oluwa yio jẹ ki wọn lọ pẹlu awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn alafia yio wà lori Israeli.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 125: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀