O. Daf 119:89-176

O. Daf 119:89-176 YBCV

Oluwa, lai, ọ̀rọ rẹ kalẹ li ọrun. Lati iran-diran li otitọ rẹ; iwọ ti fi idi aiye mulẹ, o si duro. Nwọn duro di oni nipa idajọ rẹ: nitori pe iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn. Bikoṣepe bi ofin rẹ ti ṣe inu-didùn mi, emi iba ti ṣegbe ninu ipọnju mi. Lai emi kì yio gbagbe ẹkọ́ rẹ; nitori pe awọn ni iwọ fi sọ mi di ãye. Tirẹ li emi, gbà mi; nitori ti emi wá ẹkọ́ rẹ. Awọn enia buburu ti duro dè mi lati pa mi run: ṣugbọn emi o kiyesi ẹri rẹ. Emi ti ri opin ohun pipé gbogbo: ṣugbọn aṣẹ rẹ gbõro gidigidi. Emi ti fẹ ofin rẹ to! iṣaro mi ni li ọjọ gbogbo. Nipa aṣẹ rẹ iwọ mu mi gbọ́n jù awọn ọta mi lọ: nitori ti o wà pẹlu mi lailai. Emi ni iyè ninu jù gbogbo awọn olukọ mi lọ, nitoripe ẹri rẹ ni iṣaro mi. Oye ye mi jù awọn àgba lọ, nitori ti mo pa ẹkọ́ rẹ mọ́. Mo ti fà ẹsẹ mi sẹhin kuro nipa ọ̀na ibi gbogbo, ki emi ki o le pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Emi kò yà kuro ni idajọ rẹ: nitoripe iwọ li o kọ́ mi. Ọ̀rọ rẹ ti dùn mọ́ mi li ẹnu to! jù oyin lọ li ẹnu mi! Nipa ẹkọ́ rẹ emi ni iyè ninu: nitorina mo korira ọ̀na eke gbogbo. Ọ̀rọ rẹ ni fitila fun ẹsẹ̀ mi, ati imọlẹ si ipa ọ̀na mi. Emi ti bura, emi o si mu u ṣẹ, pe, emi o pa idajọ ododo rẹ mọ́. A pọ́n mi loju gidigidi: Oluwa sọ mi di ãye, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Emi bẹ̀ ọ, Oluwa, gbà ọrẹ atinuwa ẹnu mi, ki o si kọ́ mi ni idajọ rẹ. Ọkàn mi wà li ọwọ mi nigbagbogbo: emi kò si gbagbe ofin rẹ. Awọn enia buburu ti dẹkun silẹ fun mi: ṣugbọn emi kò ṣina kuro nipa ẹkọ́ rẹ. Ẹri rẹ ni ogún mi lailai: nitori awọn li ayọ̀ inu mi. Emi ti fà aiya mi si ati pa ilana rẹ mọ́ nigbagbogbo, ani de opin. Emi korira oniye meji: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ. Iwọ ni ibi ipamọ́ mi ati asà mi: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ. Kuro lọdọ mi, ẹnyin oluṣe-buburu: emi o si pa ofin Ọlọrun mi mọ́. Gbé mi soke gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ, ki emi ki o le yè: ki o má si jẹ ki oju ireti mi ki o tì mi. Gbé mi soke, emi o si wà li ailewu: emi o si juba ìlana rẹ nigbagbogbo. Iwọ ti tẹ̀ gbogbo awọn ti o ṣina kuro ninu ilana rẹ mọlẹ: nitori pe ẹ̀tan ni ironu wọn. Iwọ ṣá gbogbo awọn enia buburu aiye tì bi ìdarọ́: nitorina emi fẹ ẹri rẹ. Ara mi warìri nitori ìbẹru rẹ; emi si bẹ̀ru idajọ rẹ. Emi ti ṣe idajọ ati ododo: iwọ kì yio jọwọ mi lọwọ fun awọn aninilara mi. Ṣe onigbọwọ fun iranṣẹ rẹ fun rere: máṣe jẹ ki awọn agberaga ki o ni mi lara. Oju kún mi nitori igbala rẹ, ati nitori ọ̀rọ ododo rẹ. Ṣe si iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi ãnu rẹ, ki o si kọ́ mi ni ilana rẹ. Iranṣẹ rẹ li emi: fun mi li oye, emi o si mọ̀ ẹri rẹ. Oluwa, o to akokò fun ọ lati ṣiṣẹ: nitori ti nwọn ti sọ ofin rẹ di ofo. Nitorina emi fẹ aṣẹ rẹ jù wura, ani, jù wura didara lọ. Nitorina emi kà gbogbo ẹkọ́ rẹ si otitọ patapata: emi si korira gbogbo ọ̀na eke. Iyanu li ẹri rẹ: nitorina li ọkàn mi ṣe pa wọn mọ́. Ifihan ọ̀rọ rẹ funni ni imọlẹ; o si fi oye fun awọn òpe. Emi yà ẹnu mi, emi mí hẹlẹ: nitori ti ọkàn mi fà si aṣẹ rẹ. Iwọ bojuwò mi; ki o si ṣãnu fun mi, gẹgẹ bi iṣe rẹ si awọn ti o fẹ orukọ rẹ. Fi iṣisẹ mi mulẹ ninu ọ̀rọ rẹ: ki o má si jẹ ki ẹ̀ṣẹkẹṣẹ ki o jọba lori mi. Gbà mi lọwọ inilara enia; bẹ̃li emi o si ma pa ẹkọ́ rẹ mọ́. Ṣe oju rẹ ki o mọlẹ si iranṣẹ rẹ lara; ki o si kọ mi ni ilana rẹ. Odò omi ṣàn silẹ li oju mi nitori nwọn kò pa ofin rẹ mọ́. Olododo ni iwọ, Oluwa, ati diduro-ṣinṣin ni idajọ rẹ. Iwọ paṣẹ ẹri rẹ li ododo ati otitọ gidigidi. Itara mi ti pa mi run nitori ti awọn ọta mi ti gbagbe ọ̀rọ rẹ. Funfun gbò li ọ̀rọ rẹ: nitorina ni iranṣẹ rẹ ṣe fẹ ẹ. Emi kere ati ẹni ẹ̀gan ni: ṣugbọn emi kò gbagbe ẹkọ́ rẹ. Ododo rẹ ododo lailai ni, otitọ si li ofin rẹ. Iyọnu ati àrokan dì mi mu: ṣugbọn aṣẹ rẹ ni inu-didùn mi. Ododo ẹri rẹ aiye-raiye ni: fun mi li oye, emi o si yè. Tinu-tinu mi gbogbo ni mo fi kigbe; Oluwa, da mi lohùn; emi o pa ilana rẹ mọ́. Emi kigbe si ọ; gbà mi là, emi o si ma pa ẹri rẹ mọ́. Emi ṣaju kutukutu owurọ, emi ke: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ. Oju mi ṣaju iṣọ-oru, ki emi ki o le ma ṣe iṣaro ninu ọ̀rọ rẹ. Gbohùn mi gẹgẹ bi ãnu rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ. Awọn ti nlepa ìwa-ika sunmọ itosi: nwọn jina si ofin rẹ. Oluwa, iwọ wà ni itosi: otitọ si ni gbogbo aṣẹ rẹ. Lati inu ẹri rẹ, emi ti mọ̀ nigba atijọ pe, iwọ ti fi idi wọn mulẹ lailai. Wò ipọnju mi, ki o si gbà mi: nitori ti emi kò gbagbe ofin rẹ. Gbà ẹjọ mi rò, ki o rà mi pada: sọ mi di ãye nipa ọ̀rọ rẹ. Igbala jina si awọn enia buburu: nitori ti nwọn kò wá ilana rẹ. Ọ̀pọ ni irọnu ãnu rẹ, Oluwa: sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ. Ọ̀pọ li awọn oninunibini mi ati awọn ọta mi; ṣugbọn emi kò fà sẹhin kuro ninu ẹri rẹ. Emi wò awọn ẹlẹtan, inu mi si bajẹ; nitori ti nwọn kò pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Wò bi emi ti fẹ ẹkọ́ rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi ãnu rẹ. Otitọ ni ipilẹṣẹ ọ̀rọ rẹ; ati olukulùku idajọ ododo rẹ duro lailai. Awọn ọmọ-alade ṣe inunibini si mi li ainidi: ṣugbọn ọkàn mi warìri nitori ọ̀rọ rẹ. Emi yọ̀ si ọ̀rọ rẹ, bi ẹniti o ri ikogun pupọ. Emi korira, mo si ṣe họ̃ si eke ṣiṣe: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ. Nigba meje li õjọ li emi nyìn ọ nitori ododo idajọ rẹ. Alafia pupọ̀ li awọn ti o fẹ ofin rẹ ni: kò si si ohun ikọsẹ fun wọn. Oluwa, emi ti nreti igbala rẹ, emi si ṣe aṣẹ rẹ. Ọkàn mi ti pa ẹri rẹ mọ́; emi si fẹ wọn gidigidi. Emi ti npa ẹkọ́ ati ẹri rẹ mọ́; nitori ti gbogbo ọ̀na mi mbẹ niwaju rẹ. Oluwa, jẹ ki ẹkún mi ki o sunmọ iwaju rẹ: fun mi li oye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Jẹ ki ẹ̀bẹ mi ki o wá siwaju rẹ: gbà mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Ete mi yio sọ iyìn jade, nigbati iwọ ba ti kọ́ mi ni ilana rẹ. Ahọn mi yio sọ niti ọ̀rọ rẹ: nitori pe ododo ni gbogbo aṣẹ rẹ. Jẹ ki ọwọ rẹ ki o ràn mi lọwọ; nitori ti mo ti yàn ẹkọ rẹ. Oluwa, ọkàn mi ti fà si igbala rẹ; ofin rẹ si ni didùn-inu mi. Jẹ ki ọkàn mi ki o wà lãye, yio si ma yìn ọ; si jẹ ki idajọ rẹ ki o ma ràn mi lọwọ. Emi ti ṣina kiri bi agutan ti o nù; wá iranṣẹ rẹ nitori ti emi kò gbagbe aṣẹ rẹ.