O. Daf 119:49-64

O. Daf 119:49-64 YBCV

Ranti ọ̀rọ nì si ọmọ-ọdọ rẹ, ninu eyiti iwọ ti mu mi ṣe ireti. Eyi ni itunu mi ninu ipọnju mi: nitori ọ̀rọ rẹ li o sọ mi di ãye. Awọn agberaga ti nyọ-ṣuti si mi gidigidi: sibẹ emi kò fa sẹhin kuro ninu ofin rẹ. Oluwa, emi ranti idajọ atijọ; emi si tu ara mi ninu. Mo ni ibinujẹ nla nitori awọn enia buburu ti o kọ̀ ofin rẹ silẹ. Ilana rẹ li o ti nṣe orin mi ni ile atipo mi. Emi ti ranti orukọ rẹ Oluwa, li oru, emi si ti pa ofin rẹ mọ́. Eyi ni mo ni nitori ti mo pa ẹkọ rẹ mọ́. Oluwa, iwọ ni ipin mi: emi ti wipe, emi o pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Emi ti mbẹ̀bẹ oju-rere rẹ tinutinu mi gbogbo: ṣãnu fun mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Emi rò ọ̀na mi, mo si yi ẹsẹ mi pada si ẹri rẹ. Emi yara, emi kò si lọra lati pa ofin rẹ mọ́. Okùn awọn enia buburu ti yi mi ka: ṣugbọn emi kò gbagbe ofin rẹ. Lãrin ọganjọ emi o dide lati dupẹ fun ọ nitori ododo idajọ rẹ. Ẹgbẹ gbogbo awọn ti o bẹ̀ru rẹ li emi, ati ti awọn ti npa ẹkọ́ rẹ mọ́. Oluwa, aiye kún fun ãnu rẹ: kọ́ mi ni ilana rẹ.