O. Daf 110:1-7

O. Daf 110:1-7 YBCV

OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ ọ̀tún mi, titi emi o fi sọ awọn ọta rẹ di apoti-itisẹ rẹ. Oluwa yio nà ọpá agbara rẹ lati Sioni wá: iwọ jọba larin awọn ọta rẹ. Awọn enia rẹ yio jẹ ọrẹ atinuwá li ọjọ ijade-ogun rẹ, ninu ẹwà ìwà-mimọ́: lati inu owurọ wá, iwọ ni ìri ewe rẹ. Oluwa ti bura, kì yio si yi ọkàn pada pe, Iwọ li alufa titi lai nipa ẹsẹ ti Melkisedeki. Oluwa li ọwọ ọtún rẹ ni yio lù awọn ọba jalẹ li ọjọ ibinu rẹ̀. Yio ṣe idajọ lãrin awọn keferi, yio fi okú kún ibi wọnni; yio fọ́ ori lori ilẹ pupọ̀. Yio ma mu ninu odò na li ọ̀na: nitorina ni yio ṣe gbé ori soke.