O. Daf 110
110
OLUWA ati Àyànfẹ́ Ọba Rẹ̀
1OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ ọ̀tún mi, titi emi o fi sọ awọn ọta rẹ di apoti-itisẹ rẹ.
2Oluwa yio nà ọpá agbara rẹ lati Sioni wá: iwọ jọba larin awọn ọta rẹ.
3Awọn enia rẹ yio jẹ ọrẹ atinuwá li ọjọ ijade-ogun rẹ, ninu ẹwà ìwà-mimọ́: lati inu owurọ wá, iwọ ni ìri ewe rẹ.
4Oluwa ti bura, kì yio si yi ọkàn pada pe, Iwọ li alufa titi lai nipa ẹsẹ ti Melkisedeki.
5Oluwa li ọwọ ọtún rẹ ni yio lù awọn ọba jalẹ li ọjọ ibinu rẹ̀.
6Yio ṣe idajọ lãrin awọn keferi, yio fi okú kún ibi wọnni; yio fọ́ ori lori ilẹ pupọ̀.
7Yio ma mu ninu odò na li ọ̀na: nitorina ni yio ṣe gbé ori soke.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
O. Daf 110: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.