O. Daf 107

107
IWE KARUN-UN
(O. Daf 107—150)
Yíyin OLUWA fún Oore Rẹ̀
1Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, nitori ti o ṣeun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
2Jẹ ki awọn ẹni-irapada Oluwa ki o wi bẹ̃, ẹniti o rà pada kuro ni ọwọ ọta nì.
3O si kó wọn jọ lati ilẹ wọnnì wá, lati ila-õrun wá, ati lati ìwọ-õrun, lati ariwa, ati lati okun wá.
4Nwọn nrìn ka kiri li aginju ni ibi ti ọ̀na kò si: nwọn kò ri ilu lati ma gbe.
5Ebi pa wọn, ongbẹ si gbẹ wọn, o rẹ̀ ọkàn wọn ninu wọn.
6Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ́ wọn,
7O si mu wọn jade nipa ọ̀na titọ, ki nwọn ki o le lọ si ilu ti nwọn o ma gbe.
8Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia!
9Nitori ti o tẹ́ ifẹ ọkàn lọrun, o si fi ire kún ọkàn ti ebi npa.
10Iru awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ti a dè ninu ipọnju ati ni irin;
11Nitori ti nwọn ṣọ̀tẹ si ọ̀rọ Ọlọrun, nwọn si gàn imọ Ọga-ogo:
12Nitorina o fi lãla rẹ̀ aiya wọn silẹ: nwọn ṣubu, kò si si oluranlọwọ.
13Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si gbà wọn ninu iṣẹ́ wọn.
14O mu wọn jade kuro ninu òkunkun ati ojiji ikú, o si fa ìde wọn ja.
15Enia iba ma yìn Oluwa: nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia.
16Nitori ti o fọ ilẹkun idẹ wọnni, o si ke ọpa-idabu irin wọnni li agbedemeji.
17Aṣiwere nitori irekọja wọn, ati nitori ẹ̀ṣẹ wọn, oju npọ́n wọn.
18Ọkàn wọn kọ̀ onjẹ-konjẹ; nwọn si sunmọ́ eti ẹnu-ọ̀na ikú.
19Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si gbà wọn ninu iṣẹ́ wọn.
20O rán ọ̀rọ rẹ̀, o si mu wọn lara da, o si gbà wọn kuro ninu iparun wọn.
21Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia.
22Si jẹ ki nwọn ki o ru ẹbọ ọpẹ, ki nwọn ki o si fi orin ayọ̀ sọ̀rọ iṣẹ rẹ̀.
23Awọn ti nsọkalẹ lọ si okun ninu ọkọ̀, ti nwọn nṣiṣẹ ninu omi nla.
24Awọn wọnyi ri iṣẹ Oluwa, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ ninu ibú.
25Nitori ti o paṣẹ, o si mu ìji fẹ, ti o gbé riru rẹ̀ soke.
26Nwọn gòke lọ si ọrun, nwọn si tún sọkalẹ lọ si ibú; ọkàn wọn di omi nitori ipọnju.
27Nwọn nta gbọ̀ngbọ́n sihin sọhun, nwọn nta gbọ̀ngbọ́n bi ọmuti enia, ọgbọ́n wọn si de opin.
28Nigbana ni nwọn kigbe pè Oluwa ninu ipọnju wọn, o si yọ wọn kuro ninu iṣẹ́ wọn.
29O sọ ìji di idakẹ-rọrọ́, bẹ̃ni riru omi rẹ̀ duro jẹ.
30Nigbana ni nwọn yọ̀, nitori ti ara wọn balẹ; bẹ̃li o mu wọn wá si ebute ifẹ wọn.
31Enia iba ma yìn Oluwa nitori ore rẹ̀, ati nitori iṣẹ iyanu rẹ̀ si awọn ọmọ enia!
32Ki nwọn ki o gbé e ga pẹlu ni ijọ enia, ki nwọn ki o si yìn i ninu ijọ awọn àgba.
33O sọ odò di aginju, ati orisun omi di ilẹ gbigbẹ;
34Ilẹ eleso di aṣálẹ̀, nitori ìwa-buburu awọn ti o wà ninu rẹ̀.
35O sọ aginju di adagun omi, ati ilẹ gbigbẹ di orisun omi.
36Nibẹ li o si mu awọn ti ebi npa joko, ki nwọn ki o le tẹ ilu do, lati ma gbe.
37Lati fún irugbin si oko, ki nwọn si gbìn àgbala ajara, ti yio ma so eso ọ̀pọlọpọ.
38O busi i fun wọn pẹlu, bẹ̃ni nwọn si pọ̀ si i gidigidi; kò si jẹ ki ẹran-ọ̀sin wọn ki o fà sẹhin.
39Ẹ̀wẹ, nwọn bùku, nwọn si fà sẹhin, nipa inira, ipọnju, ati ikãnu.
40O dà ẹ̀gan lù awọn ọmọ-alade, o si mu wọn rìn kiri ni ijù, nibiti ọ̀na kò si.
41Sibẹ o gbé talaka leke kuro ninu ipọnju, o si ṣe idile wọnni bi agbo-ẹran.
42Awọn ẹni diduro-ṣinṣin yio ri i, nwọn o si yọ̀: gbogbo ẹ̀ṣẹ ni yio si pa ẹnu rẹ̀ mọ.
43Ẹniti o gbọ́n, yio si kiyesi nkan wọnyi; awọn na li oye iṣeun-ifẹ Oluwa yio ma ye.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 107: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀