Nwọn ṣe ẹgbọrọ malu ni Horebu, nwọn si foribalẹ fun ere didà. Bayi ni nwọn pa ogo wọn dà si àworan malu ti njẹ koriko. Nwọn gbagbe Ọlọrun, Olugbala wọn, ti o ti ṣe ohun nla ni ilẹ Egipti. Iṣẹ iyanu ni ilẹ Hamu, ati ohun ẹ̀ru lẹba Okun pupa. Nitorina li o ṣe wipe, on o run wọn, iba máṣe pe Mose, ayanfẹ rẹ̀, duro niwaju rẹ̀ li oju-ẹya na, lati yi ibinu rẹ̀ pada, ki o má ba run wọn.
Kà O. Daf 106
Feti si O. Daf 106
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 106:19-23
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò