O. Daf 105:21-45

O. Daf 105:21-45 YBCV

O fi jẹ oluwa ile rẹ̀, ati ijoye gbogbo ini rẹ̀. Lati ma ṣe akoso awọn ọmọ-alade rẹ̀ nipa ifẹ rẹ̀; ati lati ma kọ́ awọn igbimọ rẹ̀ li ọgbọ́n. Israeli si wá si Egipti pẹlu; Jakobu si ṣe atipo ni ilẹ Hamu. O si mu awọn enia rẹ̀ bi si i pipọ̀-pipọ̀; o si mu wọn lagbara jù awọn ọta wọn lọ. O yi wọn li aiya pada lati korira awọn enia rẹ̀, lati ṣe arekereke si awọn iranṣẹ rẹ̀. O rán Mose iranṣẹ rẹ̀; ati Aaroni, ẹniti o ti yàn. Nwọn fi ọ̀rọ àmi rẹ̀ hán ninu wọn, ati iṣẹ iyanu ni ilẹ Hamu. O rán òkunkun, o si mu u ṣú; nwọn kò si ṣaigbọran si ọ̀rọ rẹ̀. O sọ omi wọn di ẹ̀jẹ, o si pa ẹja wọn. Ilẹ wọn mu ọ̀pọlọ jade wá li ọ̀pọlọpọ, ni iyẹwu awọn ọba wọn. O sọ̀rọ, oniruru eṣinṣin si de, ati ina-aṣọ ni gbogbo agbegbe wọn. O fi yinyin fun wọn fun òjo, ati ọwọ iná ni ilẹ wọn. O si lu àjara wọn, ati igi ọ̀pọtọ wọn; o si dá igi àgbegbe wọn. O sọ̀rọ, eṣú si de ati kokoro li ainiye. Nwọn si jẹ gbogbo ewebẹ ilẹ wọn, nwọn si jẹ eso ilẹ wọn run. O kọlu gbogbo akọbi pẹlu ni ilẹ wọn, ãyo gbogbo ipa wọn. O si mu wọn jade, ti awọn ti fadaka ati wura: kò si si alailera kan ninu ẹ̀ya rẹ̀. Inu Egipti dùn nigbati nwọn lọ: nitoriti ẹ̀ru wọn bà wọn. O nà awọsanma kan fun ibori; ati iná lati fun wọn ni imọlẹ li oru. Nwọn bère o si mu ẹiyẹ aparo wá, o si fi onjẹ ọrun tẹ wọn lọrun. O là apata, omi si tú jade; odò nṣan nibi gbigbẹ. Nitoriti o ranti ileri rẹ̀ mimọ́, ati Abrahamu iranṣẹ rẹ̀. O si fi ayọ̀ mu awọn enia rẹ̀ jade, ati awọn ayanfẹ rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀: O si fi ilẹ awọn keferi fun wọn: nwọn si jogun ère iṣẹ awọn enia na. Ki nwọn ki o le ma kiye si aṣẹ rẹ̀, ki nwọn ki o si ma pa ofin rẹ̀ mọ́. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.