O. Daf 104:1-17

O. Daf 104:1-17 YBCV

FI ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi. Oluwa, Ọlọrun mi, iwọ tobi jọjọ: ọlá ati ọla-nla ni iwọ wọ̀ li aṣọ. Ẹniti o fi imọlẹ bora bi aṣọ: ẹniti o ta ọrun bi aṣọ tita: Ẹniti o fi omi ṣe ìti igi-àja iyẹwu rẹ̀: ẹniti o ṣe awọsanma ni kẹkẹ́ rẹ̀, ẹniti o nrìn lori apa iyẹ afẹfẹ: Ẹniti o ṣe ẹfufu ni onṣẹ rẹ̀; ati ọwọ-iná ni iranṣẹ rẹ̀. Ẹniti o fi aiye sọlẹ lori ipilẹ rẹ̀, ti kò le ṣipò pada lailai. Iwọ fi ibu omi bò o mọlẹ bi aṣọ: awọn omi duro lori òke nla. Nipa ibawi rẹ nwọn sá; nipa ohùn ãra rẹ, nwọn yara lọ. Awọn òke nla nru soke; awọn afonifoji nsọkalẹ si ibi ti iwọ ti fi lelẹ fun wọn. Iwọ ti pa àla kan ki nwọn ki o má le kọja rẹ̀; ki nwọn ki o má tun pada lati bò aiye mọlẹ. Iwọ ran orisun si afonifoji, ti nṣàn larin awọn òke. Awọn ni nfi omi mimu fun gbogbo ẹranko igbẹ: awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ npa ongbẹ wọn; Lẹba wọn li awọn ẹiyẹ oju-ọrun yio ni ile wọn, ti nkọrin lãrin ẹka igi. O mbomi rin awọn òke lati iyẹwu rẹ̀ wá: ère iṣẹ ọwọ rẹ tẹ́ aiye lọrun. O mu koriko dagba fun ẹran, ati ewebẹ fun ìlo enia: ki o le ma mu onjẹ jade lati ilẹ wá; Ati ọti-waini ti imu inu enia dùn, ati oróro ti imu oju rẹ̀ dan, ati onjẹ ti imu enia li aiya le. Igi Oluwa kún fun oje, igi kedari Lebanoni, ti o ti gbìn. Nibiti awọn ẹiyẹ ntẹ́ itẹ́ wọn: bi o ṣe ti àkọ ni, igi firi ni ile rẹ̀.