Aiya mi lù, o si rọ bi koriko; tobẹ̃ ti mo gbagbe lati jẹ onjẹ mi. Nitori ohùn ikerora mi, egungun mi lẹ̀ mọ ẹran-ara mi. Emi dabi ẹiyẹ ofú ni iju: emi dabi owiwi ibi ahoro. Emi nṣọra, emi dabi ologoṣẹ nikan ni ori ile. Awọn ọta mi ngàn mi li ọjọ gbogbo; ati awọn ti nṣe ikanra si mi, nwọn fi mi bu. Emi sa jẹ ẽru bi onjẹ, emi si dà ohun mimu mi pọ̀ pẹlu omije. Nitori ikannu ati ibinu rẹ; nitori iwọ ti gbé mi soke, iwọ si gbé mi ṣanlẹ. Ọjọ mi dabi ojiji ti o nfà sẹhin; emi si nrọ bi koriko.
Kà O. Daf 102
Feti si O. Daf 102
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 102:4-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò