O. Daf 101:1-5

O. Daf 101:1-5 YBCV

EMI o kọrin ãnu ati ti idajọ: Oluwa, si ọ li emi o ma kọrin. Emi o ma rìn ìrin mi pẹlu ọgbọ́n li ọ̀na pipé. Nigbawo ni iwọ o tọ̀ mi wá! emi o ma rìn ninu ile mi pẹlu aiya pipé. Emi ki yio gbé ohun buburu siwaju mi: emi korira iṣẹ awọn ti o yapa, kì yio fi ara mọ mi. Aiya ṣiṣo yio kuro lọdọ mi: emi kì yio mọ̀ enia buburu. Ẹnikẹni ti o ba nsọ̀rọ ẹnikeji rẹ̀ lẹhin, on li emi o ke kuro: ẹniti o ni ìwo giga ati igberaga aiya, on li emi kì yio jẹ fun.