ỌGBỌ́N ti kọ́ ile rẹ̀, o si gbẹ́ ọwọ̀n rẹ̀ meje:
O ti pa ẹran rẹ̀; o ti ṣe àdalu ọti-waini rẹ̀; o si ti tẹ́ tabili rẹ̀.
O ti ran awọn ọmọbinrin rẹ̀ jade, o nke lori ibi giga ilu, pe,
Ẹnikẹni ti o ṣe òpe ki o yà si ihin: fun ẹniti oye kù fun, o wipe,
Wá, jẹ ninu onjẹ mi, ki o si mu ninu ọti-waini mi ti mo dàlu.
Kọ̀ iwere silẹ ki o si yè; ki o si ma rìn li ọ̀na oye.
Ẹniti o ba ba ẹlẹgàn wi, yio gba itiju fun ara rẹ̀, ati ẹniti o ba ba enia buburu wi yio gbà àbuku rẹ̀.
Máṣe ba ẹlẹgàn wi, ki o má ba korira rẹ, ba ọlọgbọ́n enia wi, yio si ma fẹ ọ.
Fi ẹkọ́ fun ọlọgbọ́n enia, yio si ma gbọ́n siwaju, kọ́ enia olõtọ, yio si ma fẹ ọ.
Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ọgbọ́n: ati ìmọ Ẹni-Mimọ́ li oye.
Nitori nipasẹ mi li ọjọ rẹ yio ma lé si i, ati ọdun ìye rẹ yio si ma lé si i.
Bi iwọ ba gbọ́n, iwọ o gbọ́n fun ara rẹ: ṣugbọn bi iwọ ba iṣe ẹlẹgàn, iwọ nikan ni yio rù u.
Alaroye li aṣiwere obinrin: òpe ni kò si mọ̀ nkan.
O sa joko li ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀, lori apoti, ni ibi giga ilu.
Lati ma pè awọn ti nkọja nibẹ, ti nrìn ọ̀na ganran wọn lọ: pe,
Ẹnikẹni ti o ba ṣe òpe, ki o yà si ìhin: ẹniti oye kù fun, o wi fun u pe,
Omi ole dùn, ati onjẹ ikọkọ si ṣe didùn.
Ṣugbọn on kò mọ̀ pe awọn okú wà nibẹ: ati pe awọn alapejẹ rẹ̀ wà ni isalẹ ọrun-apadi.