Owe 8:1-36

Owe 8:1-36 YBCV

ỌGBỌ́N kò ha nkigbe bi? Oye kò ha gbé ohùn rẹ̀ soke bi? O duro li ori ibi-giga wọnni, lẹba ọ̀na, nibi ipa-ọ̀na wọnni. O nke li ẹnu-ọ̀na, ati ni ibode ilu, li atiwọ̀ oju ilẹkun. Ẹnyin enia li emi npè; ohùn mi si nkọ si awọn ọmọ enia. Ẹnyin òpe, ẹ mọ̀ ọgbọ́n: ati ẹnyin aṣiwere ki ẹnyin ki o ṣe alaiya oye. Ẹ gbọ́, nitori ti emi o sọ̀rọ ohun ti o dara, ati ṣiṣi ète mi yio sọ̀rọ ohun titọ. Nitori ti ẹnu mi yio sọ̀rọ otitọ; ìwa-buburu si ni irira fun ète mi. Ninu ododo ni gbogbo ọ̀rọ ẹnu mi; kò si ẹ̀tan kan tabi arekereke ninu wọn. Gbangba ni gbogbo wọn jasi fun ẹniti o yé, o si tọ́ fun awọn ti o nwá ìmọ ri. Gbà ẹkọ mi, kì si iṣe fadaka; si gbà ìmọ jù wura àṣayan lọ. Nitori ti ìmọ jù iyùn lọ; ohun gbogbo ti a le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e. Emi ọgbọ́n li o mba imoye gbe, emi ìmọ si ri imoye ironu. Ibẹ̀ru Oluwa ni ikorira ibi: irera, ati igberaga, ati ọ̀na ibi, ati ẹnu arekereke, ni mo korira. Temi ni ìmọ ati ọgbọ́n ti o yè: emi li oye, emi li agbara. Nipasẹ mi li ọba nṣe akoso, ti awọn olori si nlàna otitọ. Nipasẹ mi li awọn ijoye nṣolori, ati awọn ọ̀lọtọ̀, ani gbogbo awọn onidajọ aiye. Mo fẹ awọn ti o fẹ mi; awọn ti o si wá mi ni kutukutu yio ri mi. Ọrọ̀ ati ọlá mbẹ lọwọ mi, ani ọrọ̀ daradara ati ododo. Ere mi ta wura yọ; nitõtọ, jù wura daradara lọ: ati ọrọ̀ mi jù fadaka àṣayan lọ. Emi nrìn li ọ̀na ododo, larin ipa-ọ̀na idajọ: Ki emi ki o le mu awọn ti o fẹ mi jogun ohun-ini mi, emi o si fi kún iṣura wọn. Oluwa pèse mi ni ipilẹṣẹ ìwa rẹ̀, ṣaju iṣẹ rẹ̀ atijọ. A ti yàn mi lati aiyeraiye, lati ipilẹṣẹ, tabi ki aiye ki o to wà. Nigbati ọgbun kò si, a ti bi mi; nigbati kò si orisun ti o kún fun omi pipọ. Ki a to fi idi awọn òke-nla sọlẹ, ṣãju awọn òke li a ti bi mi: Nigbati kò ti ida aiye, tabi pẹ̀tẹlẹ, tabi ori erupẹ aiye. Nigbati o nṣe ipilẹ awọn ọrun, emi wà nibẹ: nigbati o fi oṣuwọn ayika le oju ọgbun. Nigbati o sọ awọsanma lọjọ̀ soke: nigbati o fi agbara fun orisun ibu: Nigbati o fi aṣẹ rẹ̀ fun okun, ki omi rẹ̀ ki o máṣe kọja ẹnu rẹ̀: ati ofin rẹ̀ fun ipilẹ aiye. Nigbana, emi wà lọdọ rẹ̀, bi oniṣẹ: emi si jẹ didùn-inu rẹ̀ lojojumọ, emi nyọ̀ nigbagbogbo niwaju rẹ̀; Emi nyọ̀ ni ibi-itẹdo aiye rẹ̀: didùn-inu mi si wà sipa awọn ọmọ enia. Njẹ nisisiyi, ẹ fetisi temi, ẹnyin ọmọ: nitoripe ibukún ni fun awọn ti o tẹle ọ̀na mi: Gbọ́ ẹkọ́, ki ẹnyin ki o si gbọ́n, má si ṣe jẹ ki o lọ. Ibukún ni fun ẹniti o gbọ́ temi, ti o nṣọ́ ẹnu-ọ̀na mi lojojumọ, ti o si nduro ti opó ẹnu-ilẹkun mi. Nitoripe ẹniti o ri mi, o ri ìye, yio si ri ojurere Oluwa. Ṣugbọn ẹniti o ṣẹ̀ mi, o ṣe ọkàn ara rẹ̀ nikà: gbogbo awọn ti o korira mi, nwọn fẹ ikú.