Owe 4:25-27

Owe 4:25-27 YBCV

Jẹ ki oju rẹ ki o ma wò ọkankan gan, ki ipenpeju rẹ ki o ma wò gan niwaju rẹ. Ronu ipa-ọ̀na rẹ, gbogbo ọ̀na rẹ ni yio si fi idi mulẹ. Máṣe yà si apa ọtun tabi si apa òsi, ṣi ẹsẹ rẹ kuro ninu ibi.