Owe 4:20-23

Owe 4:20-23 YBCV

Ọmọ mi, fetisi ọ̀rọ mi; dẹti rẹ silẹ si ọ̀rọ mi. Máṣe jẹ ki nwọn ki o lọ kuro li oju rẹ; pa wọn mọ́ li ãrin aiya rẹ. Nitori ìye ni nwọn iṣe fun awọn ti o wá wọn ri, ati imularada si gbogbo ẹran-ara wọn. Jù gbogbo ohun ipamọ́, pa aiya rẹ mọ́; nitoripe lati inu rẹ̀ wá ni orisun ìye.