Fi ohun-ini rẹ bọ̀wọ fun Oluwa, ati lati inu gbogbo akọbi ibisi-oko rẹ: Bẹ̃ni aká rẹ yio kún fun ọ̀pọlọpọ, ati agbá rẹ yio si kún fun ọti-waini titun. Ọmọ mi, máṣe kọ̀ ibawi Oluwa; bẹ̃ni ki agara itọ́ni rẹ̀ ki o máṣe dá ọ: Nitoripe ẹniti Oluwa fẹ on ni itọ́, gẹgẹ bi baba ti itọ́ ọmọ ti inu rẹ̀ dùn si. Ibukún ni fun ọkunrin na ti o wá ọgbọ́n ri, ati ọkunrin na ti o gbà oye. Nitori ti òwo rẹ̀ ju òwo fadaka lọ, ère rẹ̀ si jù ti wura daradara lọ. O ṣe iyebiye jù iyùn lọ: ati ohun gbogbo ti iwọ le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e. Ọjọ gigùn mbẹ li ọwọ ọtún rẹ̀; ati li ọwọ osì rẹ̀, ọrọ̀ ati ọlá.
Kà Owe 3
Feti si Owe 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Owe 3:9-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò