Owe 29:1-27

Owe 29:1-27 YBCV

ẸNITI a ba mbawi ti o wà ọrùn kì, yio parun lojiji, laisi atunṣe. Nigbati awọn olododo wà lori oyè, awọn enia a yọ̀; ṣugbọn nigbati enia buburu ba gori oyè, awọn enia a kẹdùn. Ẹnikẹni ti o fẹ ọgbọ́n, a mu baba rẹ̀ yọ̀: ṣugbọn ẹniti o mba panṣaga kẹgbẹ, a ba ọrọ̀ rẹ̀ jẹ. Nipa idajọ li ọba imu ilẹ tòro: ṣugbọn ẹniti o ba ngbà ọrẹ a bì i ṣubu. Ẹniti o npọ́n ẹnikeji rẹ̀ ta àwọn silẹ fun ẹsẹ rẹ̀. Ninu irekọja enia ibi, ikẹkùn mbẹ: ṣugbọn olododo a ma kọrin, a si ma yọ̀. Olododo a ma rò ọ̀ran talaka: ṣugbọn enia buburu kò ṣú si i lati rò o. Awọn ẹlẹgàn enia da irukerudo si ilu: ṣugbọn awọn ọlọgbọ́n enia ṣẹ́ri ibinu kuro. Ọlọgbọ́n enia ti mba aṣiwère enia ja, bi inu li o mbi, bi ẹrín li o nrín, isimi kò si. Awọn enia-ẹ̀jẹ korira aduro-ṣinṣin: ṣugbọn awọn olododo a ma ṣe afẹri ọkàn rẹ̀. Aṣiwère a sọ gbogbo inu rẹ̀ jade: ṣugbọn ọlọgbọ́n a pa a mọ́ di ìgba ikẹhin. Bi ijoye ba feti si ọ̀rọ-eke, gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ni yio buru. Talaka ati aninilara enia pejọ pọ̀: Oluwa li o ntan imọlẹ si oju awọn mejeji. Ọba ti o fi otitọ ṣe idajọ talaka, itẹ́ rẹ̀ yio fi idi mulẹ lailai. Paṣan ati ibawi funni li ọgbọ́n: ṣugbọn ọmọ ti a ba jọwọ rẹ̀ fun ara rẹ̀, a dojuti iya rẹ̀. Nigbati awọn enia buburu ba npọ̀ si i, irekọja a pọ̀ si i: ṣugbọn awọn olododo yio ri iṣubu wọn. Tọ́ ọmọ rẹ, yio si fun ọ ni isimi; yio si fi inu-didùn si ọ li ọkàn. Nibiti iran-woli kò si, enia a yapa, ṣugbọn ibukún ni fun ẹniti o pa ofin mọ́. A kì ifi ọ̀rọ kilọ fun ọmọ-ọdọ; bi o tilẹ ye e kì yio dahùn. Iwọ ri enia ti o yara li ọ̀rọ rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ. Ẹniti o ba fi ikẹ́ tọ́ ọmọ-ọdọ rẹ̀ lati igba-ewe wá, oun ni yio jogún rẹ̀. Ẹni ibinu ru ìja soke, ati ẹni ikannu pọ̀ ni irekọja. Igberaga enia ni yio rẹ̀ ẹ silẹ: ṣugbọn onirẹlẹ ọkàn ni yio gbà ọlá. Ẹniti o kó ẹgbẹ ole korira ọkàn ara rẹ̀: o ngbọ́ ifiré, kò si fihan. Ibẹ̀ru enia ni imu ikẹkùn wá: ṣugbọn ẹnikẹni ti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa li a o gbe leke. Ọpọlọpọ enia li o nwá ojurere ijoye: ṣugbọn idajọ enia li o nti ọdọ Oluwa wá. Alaiṣõtọ enia, irira ni si awọn olododo: ẹniti o si ṣe aduro-ṣinṣin li ọ̀na, irira ni si enia buburu.