Owe 17:1-28

Owe 17:1-28 YBCV

OKELE gbigbẹ, ti on ti alafia, o san jù ile ti o kún fun ẹran-pipa ti on ti ìja. Ọlọgbọ́n iranṣẹ yio ṣe olori ọmọ ti nhùwa itiju, yio si pin ogún lãrin awọn arakunrin. Koro ni fun fadaka, ati ileru fun wura: bẹ̃li Oluwa ndan aiya wò. Oluṣe buburu fetisi ète eke; ẹni-eké a si ma kiyesi ọ̀rọ ahọn buburu. Ẹnikẹni ti o ba sín olupọnju jẹ, o gàn Ẹlẹda rẹ̀: ẹniti o ba si nyọ̀ si wahala kì yio wà li aijiya. Ọmọ ọmọ li ade arugbo: ogo awọn ọmọ si ni baba wọn. Ọ̀rọ daradara kò yẹ fun aṣiwère; bẹ̃li ète eke kò yẹ fun ọmọ-alade. Okuta iyebiye jẹ ẹ̀bun li oju ẹniti o ni i; nibikibi ti o yi si, a ṣe rere. Ẹniti o bò ẹ̀ṣẹ mọlẹ, o nwá ifẹ; ṣugbọn ẹniti o tun ọ̀ran hú silẹ, o yà ọrẹ́ nipa. Ibawi wọ̀ inu ọlọgbọ́n jù ọgọrun paṣan lọ ninu aṣiwère. Ẹni-ọ̀tẹ a ma wá kiki ibi kiri; nitorina iranṣẹ ìka li a o ran si i. O yá ki ẹranko beari ti a kó li ọmọ ki o pade enia, jù aṣiwère lọ ninu wère rẹ̀. Ẹnikẹni ti o ba fi ibi san ire, ibi kì yio kuro ninu ile rẹ̀. Ẹniti o daju fun omi dabi olupilẹṣẹ ìja; nitorina fi ìja silẹ ki o to di nla. Ẹniti o da enia buburu lare, ati ẹniti o da olododo lẹbi, ani awọn mejeji irira ni loju Oluwa. Nitori kini iye owo yio ṣe wà lọwọ aṣiwère lati rà ọgbọ́n, sa wò o, kò ni oye? Ọrẹ́ a ma fẹni nigbagbogbo, ṣugbọn arakunrin li a bi fun ìgba ipọnju. Enia ti oye kù fun, a ṣe onigbọwọ, a si fi ara sọfà niwaju ọrẹ́ rẹ̀. Ẹniti o fẹ ìja, o fẹ ẹ̀ṣẹ; ẹniti o kọ́ ẹnu-ọ̀na rẹ̀ ga, o nwá iparun. Ẹniti o ni ayidayida ọkàn kì yio ri ire: ati ẹniti o ni ahọn ọ̀rọ-meji, a bọ sinu ibi. Ẹniti o bi aṣiwère, o bi i si ibinujẹ rẹ̀; baba aṣiwère kò si li ayọ̀. Inu-didùn mu imularada rere wá: ṣugbọn ibinujẹ ọkàn mu egungun gbẹ. Enia buburu mu ẹ̀bun lati iṣẹpo-aṣọ lati yi ọ̀na idajọ pada. Ọgbọ́n wà niwaju ẹniti o moye; ṣugbọn oju aṣiwère mbẹ li opin ilẹ̀-aiye. Aṣiwère ọmọ ni ibinujẹ baba rẹ̀, ati kikoro ọkàn fun iya ti o bi i. Pẹlupẹlu kò dara ki a ṣẹ́ olotitọ ni iṣẹ́, tabi ki a lu ọmọ-alade nitori iṣedẽde. Ẹniti o ni ìmọ, a ṣẹ́ ọ̀rọ rẹ̀ kù: ọlọkàn tutu si li amoye enia. Lõtọ, aṣiwère, nigbati o ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́, a kà a si ọlọgbọ́n; ẹniti o ba pa ẹnu rẹ̀ mọ́ si li amoye.