Owe 16:1-33

Owe 16:1-33 YBCV

IMURA aiya, ti enia ni, ṣugbọn lati ọdọ Oluwa ni idadùn ahọn. Gbogbo ọ̀na enia li o mọ́ li oju ara rẹ̀; ṣugbọn Oluwa li o ndiwọ̀n ọkàn. Kó iṣẹ rẹ le Oluwa lọwọ, a o si fi idi ìro-inu rẹ kalẹ. Oluwa ti ṣe ohun gbogbo fun ipinnu rẹ̀: nitõtọ, awọn enia buburu fun ọjọ ibi. Olukulùku enia ti o gberaga li aiya, irira ni loju Oluwa: bi a tilẹ fi ọwọ so ọwọ, kì yio wà laijiya. Nipa ãnu ati otitọ a bò ẹ̀ṣẹ mọlẹ; ati nipa ibẹ̀ru Oluwa, enia a kuro ninu ibi. Nigbati ọ̀na enia ba wù Oluwa, On a mu awọn ọtá rẹ̀ pãpa wà pẹlu rẹ̀ li alafia. Diẹ pẹlu ododo, o san jù ọrọ̀ nla lọ laisi ẹtọ́. Aiya enia ni ngbìmọ ọ̀na rẹ̀, ṣugbọn Oluwa li o ntọ́ itẹlẹ rẹ̀. Ọrọ isọtẹlẹ mbẹ li ète ọba: ẹnu rẹ̀ kì iṣẹ̀ ni idajọ. Iwọn ati òṣuwọn otitọ ni ti Oluwa: gbogbo okuta-ìwọn àpo, iṣẹ rẹ̀ ni. Irira ni fun awọn ọba lati ṣe buburu: nitoripe nipa ododo li a ti fi idi itẹ́ kalẹ. Ete ododo ni didùn-inu awọn ọba: nwọn si fẹ ẹniti nsọ̀rọ titọ. Ibinu ọba dabi iranṣẹ ikú: ṣugbọn ọlọgbọ́n enia ni yio tù u. Ni imọlẹ oju ọba ni ìye; ojurere rẹ̀ si dabi awọsanma òjo arọkuro. Lati ni ọgbọ́n, melomelo li o san jù wura lọ; ati lati ni oye, melomelo li o dara jù fadaka lọ. Òpopo-ọ̀na awọn aduro-ṣinṣin ni ati kuro ninu ibi: ẹniti o pa ọ̀na rẹ̀ mọ́, o pa ọkàn rẹ̀ mọ́. Igberaga ni iṣaju iparun, agidi ọkàn ni iṣaju iṣubu. O san lati ṣe onirẹlẹ ọkàn pẹlu awọn talaka, jù ati ba awọn agberaga pin ikógun. Ẹniti o fi oye ṣe ọ̀ran yio ri ire; ẹniti o si gbẹkẹ le Oluwa, ibukún ni fun u. Ọlọgbọ́n aiya li a o pè li amoye: didùn-ète a si ma mu ẹkọ́ pọ̀. Oye li orisun ìye fun ẹniti o ni i: ṣugbọn ẹkọ́ aṣiwère ni iwère. Aiya ọlọgbọ́n mu ọ̀rọ ẹnu rẹ̀ gbọ́n, o si mu ẹkọ́ pọ̀ li ète rẹ̀. Ọrọ didùn dabi afara oyin, o dùn mọ ọkàn, o si ṣe ilera fun egungun. Ọ̀na kan wà ti o dabi ẹnipe o dara fun enia, ṣugbọn opin rẹ̀ li ọ̀na ikú. Ọkàn ti o nṣiṣẹ, o nṣiṣẹ fun ara rẹ̀; nitoripe ẹnu ara rẹ̀ li o nsún u ṣe e. Enia-buburu hù ìwa-ibi jade, ati li ète rẹ̀ bi ẹnipe iná jijo li o wà nibẹ. Alayidayida enia dá ìja silẹ: asọ̀rọkẹlẹ yà awọn ọrẹ́ ni ipa. Ẹni ìwa-agbara tàn aladugbo rẹ̀, a si mu u lọ si ipa-ọ̀na ti kò dara. On a di oju rẹ̀ lati gbèro ohun ayidayida: o ká ète rẹ̀ sinu, o pari ohun buburu. Ade ogo li ori ewú, bi a ba ri i li ọ̀na ododo. Ẹniti o lọra ati binu, o san jù alagbara lọ; ẹniti o si ṣe akoso ẹmi rẹ̀, o jù ẹniti o ṣẹgun ilu lọ. A ṣẹ́ keke dà si iṣẹpo aṣọ; ṣugbọn gbogbo idajọ rẹ̀ lọwọ Oluwa ni.