Owe 14:1-18

Owe 14:1-18 YBCV

ỌLUKULUKU ọlọgbọ́n obinrin ni kọ́ ile rẹ̀: ṣugbọn aṣiwere a fi ọwọ ara rẹ̀ fà a lulẹ. Ẹniti o nrìn ni iduroṣiṣin rẹ̀ o bẹ̀ru Oluwa: ṣugbọn ẹniti o ṣe arekereke li ọ̀na rẹ̀, o gàn a. Li ẹnu aṣiwere ni paṣan igberaga; ṣugbọn ète awọn ọlọgbọ́n ni yio pa wọn mọ́. Nibiti malu kò si, ibujẹ a di ofo: ṣugbọn ibisi pupọ mbẹ nipa agbara malu. Ẹlẹri olõtọ kò jẹ ṣeke: ṣugbọn ẹ̀tan li ẹlẹri eke ima sọ jade. Ẹlẹgan nwá ọgbọ́n, kò si ri i: ṣugbọn ìmọ kò ṣoro fun ẹniti oye ye. Kuro niwaju aṣiwere, ati lọdọ ẹniti kò ni ète ìmọ. Ọgbọ́n amoye ni ati moye ọ̀na rẹ̀: ṣugbọn iwere awọn aṣiwere li ẹ̀tan. Aṣiwere nfi ẹbi-ẹ̀ṣẹ ṣẹsin: ṣugbọn ojurere wà larin awọn olododo. Aiya mọ̀ ikoro ara rẹ̀; alejo kò si ni iṣe pẹlu ayọ̀ rẹ̀. Ile enia buburu li a o run: ṣugbọn agọ ẹni diduroṣinṣin ni yio ma gbilẹ. Ọ̀na kan wà ti o dabi ẹnipe o dara li oju enia, ṣugbọn opin rẹ̀ li ọ̀na ikú. Ninu ẹrín pẹlu, aiya a ma kãnu; ati li opin, ayọ̀ a di ibinujẹ. Apadasẹhin li aiya ni itẹlọrun lati inu ọ̀na ara rẹ̀: ṣugbọn enia rere lati inu ohun ti iṣe tirẹ̀. Òpe enia gbà ọ̀rọ gbogbo gbọ́: ṣugbọn amoye enia wò ọ̀na ara rẹ̀ rere. Ọlọgbọ́n enia bẹ̀ru, o si kuro ninu ibi; ṣugbọn aṣiwère gberaga, o si da ara rẹ̀ loju. Ẹniti o ba tete binu, huwa wère; ẹni eletè buburu li a korira. Awọn òpe jogun iwère; ṣugbọn awọn amoye li a fi ìmọ de li ade.