Owe 10:1-32

Owe 10:1-32 YBCV

OWE Solomoni ni wọnyi. Ọlọgbọ́n ọmọ ṣe inu-didùn baba rẹ̀, ṣugbọn aṣiwere ọmọ ni ibanujẹ iya rẹ̀. Iṣura ìwa-buburu kò li ère: ṣugbọn ododo ni igbani kuro lọwọ ikú. Oluwa kì yio jẹ ki ebi ki o pa ọkàn olododo; ṣugbọn o yi ifẹ awọn enia buburu danu. Ẹniti o ba dẹ̀ ọwọ a di talaka; ṣugbọn ọwọ awọn alãpọn ni imu ọlà wá. Ẹniti o ba kojọ ni igba-ẹ̀run li ọlọgbọ́n ọmọ: ṣugbọn ẹniti o ba nsùn ni igba ikore li ọmọ ti idoju tì ni. Ibukún wà li ori olododo: ṣugbọn ìwa-agbara ni yio bo ẹnu enia buburu. Ibukún ni iranti olõtọ: ṣugbọn orukọ enia buburu yio rà. Ọlọgbọ́n inu ni yio gbà ofin: ṣugbọn ete werewere li a o parun. Ẹniti o nrìn dede, o rìn dajudaju: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ayida ọ̀na rẹ̀, on li a o mọ̀. Ẹniti nṣẹ́ oju o mu ibanujẹ wá: ṣugbọn ète werewere li a o parun. Kanga ìye li ẹnu olododo: ṣugbọn ìwa-agbara ni yio bo ẹnu enia buburu. Irira ni irú ìja soke: ṣugbọn ifẹ bò gbogbo ẹ̀ṣẹ mọlẹ. Li ète ẹniti o moye li a ri ọgbọ́n: ṣugbọn kùmọ ni fun ẹhin ẹniti oye kù fun. Awọn ọlọgbọ́n a ma to ìmọ jọ: ṣugbọn ẹnu awọn aṣiwere sunmọ iparun. Ọrọ̀ ọlọlà ni agbára rẹ̀: aini awọn talaka ni iparun wọn. Iṣẹ olododo tẹ̀ si ìye; èro awọn enia buburu si ẹ̀ṣẹ. Ẹniti o ba pa ẹkọ́ mọ́, o wà ni ipa-ọ̀na ìye; ṣugbọn ẹniti o ba kọ̀ ibawi o ṣìna. Ẹniti o ba pa ikorira mọ́ li ète eke, ati ẹniti o ba ngba ọ̀rọ-ẹ̀hin, aṣiwere ni. Ninu ọ̀rọ pipọ, a kò le ifẹ ẹ̀ṣẹ kù: ṣugbọn ẹniti o fi ète mọ ète li o gbọ́n. Ahọn olõtọ dabi ãyo fadaka: aiya enia buburu kò ni iye lori. Ete olododo mbọ́ ọ̀pọlọpọ enia: ṣugbọn awọn aṣiwere yio kú li ailọgbọ́n. Ibukún Oluwa ni imu ni ilà, kì isi ifi lãla pẹlu rẹ̀. Bi ẹrín ni fun aṣiwere lati hu ìwa-ika: ṣugbọn ọlọgbọ́n li ẹni oye. Ibẹ̀ru enia buburu mbọwá ba a: ṣugbọn ifẹ olododo li a o fi fun u. Bi ìji ti ijà rekọja: bẹ̃li enia buburu kì yio si mọ: ṣugbọn olododo ni ipilẹ ainipẹkun. Bi ọti kikan si ehin, ati bi ẽfin si oju, bẹ̃li ọlẹ si ẹniti o rán a ni iṣẹ. Ibẹ̀ru Oluwa mu ọjọ gùn: ṣugbọn ọdun enia buburu li a o ṣẹ́ kuru. Abá olododo ayọ̀ ni yio jasi: ṣugbọn ireti enia buburu ni yio ṣegbe. Ọ̀na Oluwa jẹ́ ãbò fun ẹni iduroṣinṣin, ṣugbọn egbe ni fun awọn oniṣẹ-ẹ̀ṣẹ. A kì yio ṣi olododo ni ipo lai; ṣugbọn enia buburu kì yio gbe ilẹ̀-aiye. Ẹnu olõtọ mu ọgbọ́n jade; ṣugbọn ahọn arekereke li a o ke kuro. Ete olododo mọ̀ ohun itẹwọgba; ṣugbọn ẹnu enia buburu nsọ̀rọ arekereke.