Ẹ ni ero yi ninu nyin, eyi ti o ti wà pẹlu ninu Kristi Jesu: Ẹniti o tilẹ jẹ aworan Ọlọrun, ti kò ka a si iwọra lati ba Ọlọrun dọgba: Ṣugbọn o bọ́ ogo rẹ̀ silẹ, o si mu awọ̀ iranṣẹ, a si ṣe e ni awòran enia. Nigbati a si ti ri i ni ìri enia, o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, o si tẹriba titi di oju ikú, ani ikú ori agbelebu. Nitorina Ọlọrun pẹlu si ti gbé e ga gidigidi, o si ti fi orukọ kan fun u ti o bori gbogbo orukọ: Pe, li orukọ Jesu ni ki gbogbo ẽkun ki o mã kunlẹ, awọn ẹniti mbẹ li ọrun, ati awọn ẹniti mbẹ ni ilẹ, ati awọn ẹniti mbẹ nisalẹ ilẹ; Ati pe ki gbogbo ahọn ki o mã jẹwọ pe, Jesu Kristi ni Oluwa, fun ogo Ọlọrun Baba.
Kà Filp 2
Feti si Filp 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Filp 2:5-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò