NITORINA bi itunu kan ba wà ninu Kristi, bi iṣipẹ ifẹ kan ba si wà, bi ìdapọ ti Ẹmí kan ba wà, bi ìyọ́nu-anu ati iṣeun ba wà,
Ẹ mu ayọ̀ mi kún, ki ẹnyin ki o le jẹ oninu kanna, ki imọ̀ nyin ki o ṣọkan, ki ẹ si ni ọkàn kan.
Ẹ máṣe fi ìja tabi ogo asan ṣe ohunkohun: ṣugbọn ni irẹlẹ ọkàn ki olukuluku ro awọn ẹlomiran si ẹniti o san ju on tikararẹ̀ lọ.
Ki olukuluku nyin ki o máṣe wo ohun tirẹ̀, ṣugbọn olukuluku ohun ti ẹlomiran.
Ẹ ni ero yi ninu nyin, eyi ti o ti wà pẹlu ninu Kristi Jesu:
Ẹniti o tilẹ jẹ aworan Ọlọrun, ti kò ka a si iwọra lati ba Ọlọrun dọgba:
Ṣugbọn o bọ́ ogo rẹ̀ silẹ, o si mu awọ̀ iranṣẹ, a si ṣe e ni awòran enia.
Nigbati a si ti ri i ni ìri enia, o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, o si tẹriba titi di oju ikú, ani ikú ori agbelebu.
Nitorina Ọlọrun pẹlu si ti gbé e ga gidigidi, o si ti fi orukọ kan fun u ti o bori gbogbo orukọ:
Pe, li orukọ Jesu ni ki gbogbo ẽkun ki o mã kunlẹ, awọn ẹniti mbẹ li ọrun, ati awọn ẹniti mbẹ ni ilẹ, ati awọn ẹniti mbẹ nisalẹ ilẹ;
Ati pe ki gbogbo ahọn ki o mã jẹwọ pe, Jesu Kristi ni Oluwa, fun ogo Ọlọrun Baba.
Nitorina ẹnyin olufẹ mi, gẹgẹ bi ẹnyin ti ngbọran nigbagbogbo, kì iṣe nigbati mo wà lọdọ nyin nikan, ṣugbọn papa nisisiyi ti emi kò si, ẹ mã ṣiṣẹ igbala nyin yọri pẹlu ìbẹru ati iwarìri,
Nitoripe Ọlọrun ni nṣiṣẹ ninu nyin, lati fẹ ati lati ṣiṣẹ fun ifẹ inu rere rẹ̀.
Ẹ mã ṣe ohun gbogbo li aisi ikùnsinu ati ijiyan.
Ki ẹnyin ki o le jẹ alailẹgàn ati oniwa tutu, ọmọ Ọlọrun, alailabawọn, larin oniwà wíwọ ati alarekereke orilẹ-ede, larin awọn ẹniti a nri nyin bi imọlẹ li aiye;
Ẹ si mã na ọwọ ọ̀rọ ìye jade; ki emi ki o le ṣogo li ọjọ Kristi pe emi kò sáre lasan, bẹni emi kò si ṣe lãlã lasan.
Ani, bi a tilẹ tú mi dà sori ẹbọ ati iṣẹ isin igbagbọ́ nyin, mo yọ̀, mo si mba gbogbo nyin yọ̀ pẹlu.
Bakanna ni ki ẹnyin ki o mã yọ̀, ki ẹ si mã ba mi yọ̀ pẹlu.