Filp 1:12-26

Filp 1:12-26 YBCV

Njẹ emi fẹ ki ẹnyin ki o mọ̀, ará, pe nkan wọnni ti o de bá mi, o kuku yọri si ilọsiwaju ihinrere; Tobẹ ti idè mi gbogbo farahan ninu Kristi larin awọn ọmọ-ogun ãfin ati gbogbo awọn ẹlomiran; Ati pe ọ̀pọlọpọ awọn arakunrin ninu Oluwa, ti o ni igbẹkẹle si ìde mi nfi igboiya gidigidi sọrọ Ọlọrun laibẹru. Nitotọ awọn ẹlomiran tilẹ nfi ija ati ilara wasu Kristi; awọn ẹlomiran si nfi inu rere ṣe e. Awọn kan nfi ìja wasu Kristi, kì iṣe pẹlu õtọ inu, nwọn ngbèro lati fi ipọnju kún ìde mi: Awọn kan ẹwẹ si nfi ifẹ ṣe e, nitoriti nwọn mọ̀ pe a gbe mi dide fun idahun-ẹjọ ihinrere. Njẹ kini? bikoṣepe nibi gbogbo, iba ṣe niti àfẹ̀tànṣe tabi niti otitọ, a sa nwasu Kristi; emi si nyọ̀ nitorina, nitõtọ, emi ó si ma yọ̀. Nitoriti mo mọ̀ pe eyi ni yio yọri si igbala fun mi lati inu adura nyin wá, ati ifikún Ẹmí Jesu Kristi, Gẹgẹ bi ìnàgà ati ireti mi pe ki oju ki o máṣe tì mi li ohunkohun, ṣugbọn pẹlu igboiya gbogbo, bi nigbagbogbo, bẹ̃ nisisiyi pẹlu a o gbé Kristi ga lara mi, ibã ṣe nipa ìye, tabi nipa ikú. Nitori, niti emi, lati wà lãye jẹ Kristi, lati kú jẹ ere. Ṣugbọn bi lati wà lãye ninu ara ba jẹ eso iṣẹ mi, nigbana ohun ti emi o yàn, emi kò mọ. Ṣugbọn emi mbẹ ni iyemeji, mo ni ifẹ lati lọ ati lati wà lọdọ Kristi; nitori o dara pupọ ju: Sibẹ lati wà ninu ara jẹ anfani nitori ti nyin. Bi eyi si ti da mi loju, mo mọ̀ pe emi ó duro, emi ó si mã bá gbogbo nyin gbé fun ilọsiwaju ati ayọ̀ nyin ninu igbagbọ; Ki iṣogo nyin ki o le di pupọ gidigidi ninu Jesu Kristi ninu mi nipa ipada wá mi sọdọ nyin.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Filp 1:12-26