File 1

1
1PAULU, onde Kristi Jesu, ati Timotiu arakunrin wa, si Filemoni olufẹ ati alabaṣiṣẹ wa ọwọn,
2Ati si Affia arabinrin wa, ati si Arkippu ọmọ-ogun ẹgbẹ wa, ati si ìjọ inu ile rẹ:
3Ore-ọfẹ, ati alafia sí nyin, lati ọdọ Ọlọrun Baba wa, ati Jesu Kristi Oluwa.
Ìfẹ́ ati Igbagbọ Tí Filemoni Ní
4Emi ndupẹ lọwọ Ọlọrun mi nigbagbogbo, emi nṣe iranti rẹ ninu adura mi,
5Bi mo ti ngbọ́ ti ifẹ rẹ ati igbagbọ́ ti iwọ ni si Jesu Oluwa, ati si gbogbo awọn enia mimọ́;
6Ki idapọ igbagbọ́ rẹ le lagbara, ni imọ ohun rere gbogbo ti mbẹ ninu nyin si Kristi.
7Emi sá ni ayọ̀ pupọ ati itunu nitori ifẹ rẹ, nitoriti a tù ọkàn awọn enia mimọ́ lara lati ọwọ́ rẹ wá, arakunrin.
Ẹ̀bẹ̀ fún Onisimu
8Nitorina, bi mo tilẹ ni igboiya pupọ̀ ninu Kristi lati paṣẹ ohun ti o yẹ fun ọ,
9Ṣugbọn nitori ifẹ emi kuku bẹ̀bẹ, iru ẹni bi emi Paulu arugbo, ati nisisiyi ondè Kristi Jesu pẹlu.
10Emi bẹ̀ ọ fun ọmọ mi, ti mo bí ninu ìde mi, Onesimu:
11Nigbakan rí ẹniti o jẹ alailere fun ọ, ṣugbọn nisisiyi o lere fun ọ ati fun mi:
12Ẹniti mo rán pada, ani on tikalarẹ̀, eyini ni olufẹ mi:
13Ẹniti emi iba fẹ daduro pẹlu mi, ki o le mã ṣe iranṣẹ fun mi nipo rẹ ninu ìde ihinrere:
14Ṣugbọn li aimọ̀ inu rẹ emi kò fẹ ṣe ohun kan; ki ore rẹ ki o má ba dabi afiyanjuṣe, bikoṣe tifẹtifẹ.
15Nitori boya idi rẹ̀ li eyi ti o fi kuro lọdọ rẹ fun igba diẹ, ki iwọ ki o ba le ni i titi lai;
16Kì iṣe bi ẹrú mọ, ṣugbọn o jù ẹrú lọ, arakunrin olufẹ, papa fun mi, melomelo jubẹ̃lọ fun ọ, nipa ti ara ati nipa ti Oluwa.
17Nitorina bi iwọ ba kà mi si ẹlẹgbẹ rẹ, gbà a bi emi tikarami.
18Ṣugbọn bi o ba ti ṣẹ̀ ọ rara, tabi ti o jẹ ọ nigbese kan, kà a si mi lọrùn.
19Emi Paulu li o fi ọwọ́ ara mi kọ ọ, emi ó san a pada: ki emi má sọ fun ọ, bi o ti jẹ mi nigbese ara rẹ pẹlu.
20Nitõtọ, arakunrin, jẹ ki emi ki o ni ayọ̀ rẹ ninu Oluwa: tù ọkan mi lara ninu Kristi.
21Bi mo ti ni igbẹkẹle ni igbọràn rẹ ni mo fi kọwe si ọ: nitori mo mọ̀ pe, iwọ ó tilẹ ṣe jù bi mo ti wi lọ.
22Ati pẹlu, pese ìbuwọ̀ silẹ dè mi; nitori mo gbẹkẹle pe nipa adura nyin, a ó fi mi fun nyin.
Ìdágbére
23Epafra, ondè ẹlẹgbẹ mi ninu Kristi Jesu kí ọ;
24Marku, Aristarku, Dema, Luku, awọn olubaṣiṣẹ mi kí ọ pẹlu.
25Ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa ki o wà pẹlu ẹmí nyin. Amin.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

File 1: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀