Num 33

33
Ìrìn Àjò láti Ijipti sí Moabu
1WỌNYI ni ìrin awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá pẹlu awọn ogun wọn, nipa ọwọ́ Mose ati Aaroni.
2Mose si kọwe ijadelọ wọn gẹgẹ bi ìrin wọn, nipa aṣẹ OLUWA; wọnyi si ni ìrin wọn gẹgẹ bi ijadelọ wọn.
3Nwọn si ṣí kuro ni Ramesesi li oṣù kini, ni ijọ́ kẹdogun oṣù kini na; ni ijọ́ keji ajọ irekọja li awọn ọmọ Israeli jade pẹlu ọwọ́ giga li oju gbogbo awọn ara Egipti.
4Bi awọn ara Egipti ti nsinkú gbogbo awọn akọ́bi wọn ti OLUWA kọlù ninu wọn: lara awọn oriṣa wọn pẹlu li OLUWA ṣe idajọ.
5Awọn ọmọ Israeli si ṣí kuro ni Ramesesi, nwọn si dó si Sukkotu.
6Nwọn si ṣí kuro ni Sukkotu, nwọn si dó si Etamu, ti mbẹ leti aginjù.
7Nwọn si ṣí kuro ni Etamu, nwọn si pada lọ si Pi-hahirotu, ti mbẹ niwaju Baali-sefoni: nwọn si dó siwaju Migdolu.
8Nwọn si ṣí kuro niwaju Hahirotu, nwọn si là ãrin okun já lọ si aginjù: nwọn si rìn ìrin ijọ́ mẹta li aginjù Etamu, nwọn si dó si Mara.
9Nwọn si ṣí kuro ni Mara, nwọn si wá si Elimu: ni Elimu ni orisun omi mejila, ati ãdọrin igi ọpẹ wà; nwọn si dó sibẹ̀.
10Nwọn si ṣí kuro ni Elimu, nwọn si dó si ẹba Okun Pupa.
11Nwọn si ṣí kuro li Okun Pupa, nwọn si dó si aginjù Sini.
12Nwọn si ṣí kuro ni aginjù Sini, nwọn si dó si Dofka.
13Nwọn si ṣí kuro ni Dofka, nwọn si dó si Aluṣi.
14Nwọn si ṣí kuro ni Aluṣi, nwọn si dó si Refidimu, nibiti omi kò gbé sí fun awọn enia na lati mu.
15Nwọn si ṣí kuro ni Refidimu, nwọn si dó si aginjù Sinai.
16Nwọn si ṣí kuro ni aginjù Sinai, nwọn si dó si Kibrotu-hattaafa.
17Nwọn si ṣí kuro ni Kibrotu-hattaafa, nwọn si dó si Haserotu.
18Nwọn si ṣí kuro ni Haserotu, nwọn si dó si Ritma.
19Nwọn si ṣí kuro ni Ritma, nwọn si dó si Rimmon-peresi.
20Nwọn si ṣí kuro ni Rimmon-peresi, nwọn si dó si Libna.
21Nwọn si ṣí kuro ni Libna, nwọn si dó si Rissa.
22Nwọn si ṣí kuro ni Rissa, nwọn si dó si Kehelata.
23Nwọn si ṣí kuro ni Kehelata, nwọn si dó si òke Ṣeferi.
24Nwọn si ṣí kuro ni òke Ṣeferi, nwọn si dó si Harada.
25Nwọn si ṣí kuro ni Harada, nwọn si dó si Makhelotu.
26Nwọn si ṣí kuro ni Makhelotu, nwọn si dó si Tahati.
27Nwọn si ṣí kuro ni Tahati, nwọn si dó si Tera.
28Nwọn si ṣí kuro ni Tera, nwọn si dó si Mitka.
29Nwọn si ṣí kuro ni Mitka, nwọn si dó si Haṣmona.
30Nwọn si ṣí kuro ni Haṣmona, nwọn si dó si Moserotu.
31Nwọn si ṣí kuro ni Moserotu, nwọn si dó si Bene-jaakani.
32Nwọn si ṣí kuro ni Bene-jaakani, nwọn si dó si Hori-haggidgadi.
33Nwọn si ṣí kuro ni Hori-haggidgadi, nwọn si dó si Jotbata.
34Nwọn si ṣí kuro ni Jotbata, nwọn si dó si Abrona.
35Nwọn si ṣí kuro ni Abrona, nwọn si dó si Esion-geberi.
36Nwọn si ṣí kuro ni Esion-geberi, nwọn si dó si aginjù Sini, (ti ṣe Kadeṣi),
37Nwọn si ṣí kuro ni Kadeṣi, nwọn si dó si òke Hori, leti ilẹ Edomu.
38Aaroni alufa si gùn òke Hori lọ nipa aṣẹ OLUWA, o si kú nibẹ̀, li ogoji ọdún lẹhin ti awọn ọmọ Israeli ti ilẹ Egipti jade wá, li ọjọ́ kini oṣù karun.
39Aaroni si jẹ́ ẹni ọgọfa ọdún o le mẹta nigbati o kú li òke Hori.
40Ara Kenaani, ọba Aradi, ti ngbé ìha gusù ni ilẹ Kenaani, o gburó pe awọn ọmọ Israeli mbọ̀.
41Nwọn si ṣí kuro ni òke Hori, nwọn si dó si Salmona.
42Nwọn si ṣí ni Salmona, nwọn si dó si Punoni.
43Nwọn si ṣí kuro ni Punoni, nwọn si dó si Obotu.
44Nwọn si ṣí kuro ni Obotu, nwọn si dó si Iye-abarimu, li àgbegbe Moabu.
45Nwọn si ṣí kuro ni Iyimu, nwọn si dó si Dibon-gadi.
46Nwọn si ṣí kuro ni Dibon-gadi, nwọn si dó si Almon-diblataimu.
47Nwọn si ṣí kuro ni Almon-diblataimu, nwọn si dó si òke Abarimu, niwaju Nebo.
48Nwọn si ṣí kuro ni òke Abarimu, nwọn si dó si pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko.
49Nwọn si dó si ẹba Jordani, lati Beti-jeṣimotu titi dé Abeli-ṣittimu ni pẹtẹlẹ̀ Moabu.
Ìlànà Nípa Líla Odò Jọdani Kọjá
50OLUWA si sọ fun Mose ni pẹtẹlẹ̀ Moabu lẹba Jordani leti Jeriko, wipe,
51Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba gòke odò Jordani si ilẹ Kenaani:
52Nigbana ni ki ẹnyin ki o lé gbogbo awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; ki ẹnyin si run gbogbo aworán wọn, ki ẹnyin si run gbogbo ere didà wọn, ki ẹnyin si wó gbogbo ibi giga wọn palẹ:
53Ki ẹnyin ki o si gbà ilẹ na, ki ẹnyin ki o si ma gbé inu rẹ̀: nitoripe mo ti fi ilẹ na fun nyin lati ní i.
54Ki ẹnyin ki o si fi keké pín ilẹ na ni iní fun awọn idile nyin; fun ọ̀pọ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun diẹ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní diẹ fun: ki ilẹ-iní olukuluku ki o jẹ́ ibiti keké rẹ̀ ba bọ́ si; gẹgẹ bi ẹ̀ya awọn baba nyin ni ki ẹnyin ki o ní i.
55Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba lé awọn ara ilẹ na kuro niwaju nyin; yio si ṣe, awọn ti ẹnyin jẹ ki o kù ninu wọn yio di ẹgún si oju nyin, ati ẹgún si nyin ni ìha, nwọn o si ma yọ nyin lẹnu ni ilẹ na, ninu eyiti ẹnyin ngbé.
56Yio si ṣe, bi emi ti rò lati ṣe si wọn, bẹ̃ni emi o ṣe si nyin.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Num 33: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀